David Lyon, olùdije APC tó wọlé ìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Bayelsa

BAYELSA Image copyright OTHERS

Lẹyin ogun ọdun ti PDP ti n ṣe ijọba ni ipinlẹ Bayelsa, APC ti gba ijọba bayii.

David Lyon ni awọn eniyan dibo yan ninu eto idibo sipo gomina to waye ni Ọjọ kẹtadinlogun, Oṣu Kọkanla, ọdun 2019.

Awọn eniyan marundinlaadọta lo dije dupo naa ki Lyon to wa jawe olubori.

Wo koko ohun mẹwaa nipa gomina tuntun ti wọn dibo yan ni Bayelsa.

  • Ọmọ ọdun mọkandinlaadọta ni David Lyon Perewonrimi.
  • Agboole Olodiana ni Guusu ijọba ibilẹ Ijaw ni wọn ti bi i.
  • Gbajugbaja oniṣowo, ni amọ kii se gbogbo eniyan lo mọ ọ ni isejoba ipinlẹ Bayelsa.
  • Lyon ni olootu ile iṣe ti won ti n ṣeto idaabobo awon ara ilu tabi ile iṣe, Darlon Security.
  • O dije dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lati ṣe akoso awọn ara ẹkun Guusu Ijaw ni ọdun 2011.
  • Ogunjọ, Oṣu Kejila, ọdun 1970 ni wọn bi i ni agbeegbe Olugbori.
  • Ile iwe Alakọbẹrẹ Saint Gabriel's State School Olugbobiri, lo lọ lati ọdun 1978 si ọdun 1983.
  • O lo si ile iwe Girama Olugbobiri lati ọdun 1984 si 1988.
  • Ile iwe giga Rivers State College of Education lo ti kekọ gboye National Certificate of Education (NCE).

Ẹ máa retí láti ìpínlẹ̀ Kogi!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa akódọ̀tí táà ń gba £1,500 lóṣù níbi sàn ju Sẹ́nétọ̀ lọ ní Nàìjíríà'

David Lyon ṣe fàgbà han Douye Diri ti ẹgbẹ́ PDP ní Bayelsa

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe oludije ẹgbẹ oselu APC, David Lyon ti wọle ibo gomina to waye ni ipinlẹ Bayelsa.

Eyi ni igba akọkọ ti ẹgbẹ APC yoo wọle ibo gomina nipinlẹ Bayelsa.

Esi idibo ti ajọ INEC fi sita ṣafihan rẹ pe ẹgbẹẹgbẹrun un ibo ni Lyon fi la oludije fẹgbẹ oṣelu PDP, Douye Diri to sun mọ julọ mọlẹ.

Àjọ INEC so ìbò kíkà ní ìpínlẹ̀ Kogi rọ̀ dí aago mẹ́sàn án àárọ̀ ọjọ́ Ajé

Wo ẹni tó ń léwájú gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Kogi

Bẹ́ẹ ṣe ń retí láti Kogi àti Bayelsa, ajáwé olúborí Sri Lanka àti alátakò rẹ̀ ti fọwọ́ wẹwọ́

Iye ibo 352,552 ni Lyon ti APC fi la oludije alatako rẹ ti PDP, Duoye Diri mọlẹ toun ni ibo 133,172.

Ninu oludibo to le ni 867,000 to forukọ silẹ lati dibo ni ilu to n f'epo ṣe ọrọ̀ yii, 516,371 lo jade lọ dibo yan gómìnà wọn lọjọ ikẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019.