Power Supply: Òkùnkùn birimùbirimù ń bọ̀ bí NBET ò bá ṣàtúnṣe

Taransformer
Àkọlé àwòrán Hee! òkùnkùn birimùbirimù ń bọ ní Nàìjíríà

Àfàìmọ̀ ni kí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà má wọ inú òkùnkùn birimùbirmù lọ láìpẹ yìí bi àwọn ilé iṣẹ́ to n pín ina ọba ni Naijirià ṣe kọ láti gbana ojú ilé iṣẹ́ to n pín ina fún wọ́n iyẹn (NBET).

Wọn sọ èyí di mímọ lásìkò ti àkowé àgbà ẹgbẹ́ àwọn ilé iṣẹ to ń pín iná (APGC), Joy Ogaji pe ìpàdé àwọn oníroyin nílùú Abuja, o ṣálàyé pé ìpìnu NBET ni láti gbé idá 0.75% le àwọn (GENCO) lórí gẹ́gẹ́ bii owo ajẹmọnu fun sisanwo afẹfẹ gáàsi.

Bákan náà lo sàlàyé pé gbèsè ti NBET ti jẹ àwọn ilé iṣe to pin ina lojule dójulè ko ṣee fẹnusọ èyi to ni o ti tó Triliọnu kan Naira.

Iṣẹ́ NERC ni láti mójútó bi àwọn NBET ṣe n ra ina fun àtunta si àwọn ile iṣẹ́ ti yio pin in láti ojúlé de ojulé.

Nínú oṣu kẹsàn ọdun yìí NBET bèrè afikun 0.75% lati fi kun Gencos gẹ́gẹ́ bi owo ti wọ́n o maa gba lorukọ wọ́n fún ríra iná.

Ogaji sọ pé bo tilẹ jẹ pé Gencos fárigá nigba ti wọ́n gbe àbá náà jáde àti pé àwọn ajọ to n moju to owo ijọba àti NERC ko fọ́wọ́ sí i síbẹ̀ NBET bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.

Lásìkò to wá n bá àwọn akoròyìn sọ̀rọ̀, Ogaji ni " ǹkan ti NBET ṣe yìí lásàn le mu ki àwọn dáwọ ina pinpin dúro to si túmọ si pé inú òkùnkùn birimù ni Naijiria yóò wà.

O ni ìnà ti jo dórí pápá lori ọ̀rọ̀ wọ́n nítori gbogbo ìgbésẹ̀ ti àwọn mọ ni àwọn ti gbé to fi mọ kíkọ lẹta si NERC ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n ketí ọgbọin sii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa akódọ̀tí táà ń gba £1,500 lóṣù níbi sàn ju Sẹ́nétọ̀ lọ ní Nàìjíríà'