KogiDecides2019: Àjọ Ìsọ̀kan Yúròòpù àti Amẹ́ríkà bẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìdìbò Kogi àti Bayelsa

Aworan olori ikọ EU to n mojuto idibo Kogi ati Bayelsa Image copyright EUinNigeria
Àkọlé àwòrán KogiDecides2019: Àjọ Ìsọ̀kan Yúròòpù àti Amẹ́ríkà bẹnu àtẹ lu ìdìbò Kogi àti Bayelsa

Ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu ati ijọba orile-ede Amẹrika ti bẹnu atẹ lu bi eto idibo Gomina ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa ti ṣe lọ.

Awọn mejeeji ninu atẹjade kan ti wọn fi sita sọ pe o ku diẹ kaato bi iwa janduku, makaruru ati ibo rira ti ṣe gbode lasiko idibo naa.

Awọn aṣoju to woye eto idibo naa sọ pe ohun toju awọn ri lasiko idibo naa kọja afẹnusọ.

Wọn ni: ''A gbọ nipa awọn to ku ninu idibo naa ti awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo miran si di awati.

Gbogbo awọn to farakaasa iṣẹlẹ naa la ba mọlẹbi wọn kẹdun''

Wọn kan sara si awọn oludibo to kopa ninu idibo mejeeji to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Àkọlé àwòrán Gbogbo awọn to farakaasa iṣẹlẹ naa la ba mọlẹbi wọn kẹdun''

Bakan naa ni wọn kesi awọn alẹnulọrọ paapa julọ awọn ẹgbẹ oṣelu lati pẹtu sawọn eeyan wọn ki awọn ẹka ijọba si ri pe wọn tọ pinpin awọn to lọwọ ninu iwa ibajẹ lasiko idibo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Lasiko idibo Kogi ati Bayelsa,awọn onwoye eto idibo ke gbajare lori bi awọn janduku ti ṣe n gbe apoti idibo ti wọn si n ra ibo.

O kere tan eeyan mẹta ni iroyin sọ pe o ku ninu idibo Kogi ti wọn si ni awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo wa lara wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo