#WorldToiletDay: Nínú kó o fi omi fọ ìdi tàbí lo tííṣù fi fá a, Èwo ló rọrùn?

Tiiṣu ni ile igbọnsẹ Image copyright Getty Images

"Nilẹ Arab bi a ba n di ẹru lati rinrinajo, ohun mẹta ni a gbudọ rii daju pe a ni: iwe irina, owo ati ibi ti a le fọ idi si ni'rinajo". Eyi ni adẹrinpoṣonu ara ill Egypti Bassem Youssef sọ nibi ere itage akọkọ rẹ ni Uk gẹgẹ bi alawada.

(Ẹ̀rín kèékèé)!

Ṣe lo bẹrẹ si nii ju ọpa kan ti wọn n pe lede wọn ni shattaf (tabi bum gun) iyẹn ẹrọ kan to lee fọn omi jade to maa n wa lẹba ile igbọnsẹ igbalode fun idi fifọ.

O ni "ẹ wa, ko ye mi o, ẹ jẹ ọkan lara ilu to laju ju lagbaye, ṣugbọn to ba di ọrọ ti ẹyin wa yii, ẹyin lẹwa o." (Ha ha ha)!

Bẹẹ si ni ọpọ eeyan gba pẹlu Youssef pe ootọ lo sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Shokoleeti to ri bii pẹ̀tẹ̀ -"Chocolate pudding"

Ni ilu oyinbo, ọpọ wọn ti fẹran ki wọn maa fi nkankan nu idi ju bi wọn ba lo ile igbọnsẹ tan ju ki wọn maa bu omi ṣan idi lọ - eyi si jẹ oun to ya awọn eeyan lẹnu lagbaye.

Kẹẹ si maa wo o, omi a maa fọ idi mọ ju béébà lọ.

Awọn to ti mọ lara ki wọn maa fi omi fọ idi wa beere tọkan tọkan wi pe " ẹ wa, ṣe lootọ o tẹẹ yin lọrun lati fi tiiṣu nikan nu shokoleeti pẹ̀tẹ̀ kuro lara yin? (Ínyànmà)!

Image copyright Getty Images

Ati pe nigba ti tiiṣu ti wọ́n n lo lode oni ko le lara bii àwo sẹ̀rámííkì tawọn Greek igbaani maa n lo tabi shùkù àgbàdo tawọn Amẹrika igbaani maa n lo

(Hè hè hè hè - ẹ̀rín), gbogbo wa yoo gba pe omi ko tilẹ ki n ha ni lara to iwe to fẹlẹ ju.

Ọpọ ara ilu awọn orilẹede agbaye lo ti wa n pari abẹwo wọn sile igbọnsẹ bayii pẹlu omi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa akódọ̀tí táà ń gba £1,500 lóṣù níbi sàn ju Sẹ́nétọ̀ lọ ní Nàìjíríà'
Image copyright Getty Images

Sibẹ, ni ọpọ awọ n orilede ti ẹlẹsin musulumi pọ si, omi lilo lo wọpọ nib gẹ́gẹ́ bi ẹkọ Islam ṣe kọ nipa lilo omi fun imọtoto.

Onimọ kan to ṣewadii nipa iha ti awọn eeyan n kọ si awọn nkan eelo ile igbọnsẹ, Othman fi han pe awọn musulumi ara orilẹede Australia kan ti dara pọ mọ iwa igbe aye lilo ile igbọnsẹ igbalode ati lilo tiiṣu pọ mọ age omi to kun tabi ki wọn ṣe ẹrọ to n fọn omi sẹgbẹẹ ẹrọ igbọnsẹ wọn.

Amọṣa o, ọ̀rọ̀ imọtoto yii ko duro lọdọ awọn musulumi nikan o.

Tííṣù

Image copyright Getty Images

"O ti mọ awọn ara orilẹede India kan lara lati maa lo tiiṣu, ṣugbọn ọpọ wa la ṣi fara mọ lilo omi nigba to ba yẹ".

Othman ni "nigba ti o ba fẹ ṣebẹwo si ọrẹ rẹ to jẹ ara Indian nilẹ Amẹrika, mo lee fwọ sọya pe wọn gbe ike omi tabi ife si ẹba ile igbọnsẹ wọn".

Ẹwẹ, Othman sọ iha ti awọn eeyan kọ si lilo oriṣiriṣi beeba, o ni fun apẹrẹ akẹgbẹ oun kan ni Sheffield, UK ti lo tiiṣu rẹ tan, lo ba pada fi £20 nu idi. (Hà hà hàhà hà!)

Image copyright Getty Images

Ninu koo jokoo tabi bẹrẹ?

Idile kan, Kuo gan ti n jiroro lori ọrọ mejeji yii - ninu keeyan jokoo ya igbẹ tabi loṣoo.

Iru ile igbọnsẹ fun mejeji lo wa laye Han Dynasty (206BC-220AD) bi o tilẹ jẹ pe bibẹrẹ yẹn lo wọpọ lawọn ile igbọnsẹ itagbangba.

Koda lonii, iwadii fihan pe ida mẹta eeyan lagbaye lo maa n loṣoo ṣe 'ga.

Ka si ma parọ, fun ẹya agọ ara liloṣoo naa lo dara ju gẹgẹ bi iru ibẹrẹ yẹn ṣe maa n jẹ ko jade wọọrọwọ. (Hmmmmmn!)

Image copyright Getty Images