World Toilet Day: Wo àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ kí èèyàn máa gbọnsẹ̀ síbi tó bá wù ú

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Ìgbẹ́ tí wọ́n ń yà síbí kìí jẹ kí oníbàárà wá sọ́dọ̀ wa'

Iru ọjọ oni ni gbogbo ọdun ni ayajọ ọjọ igbọnsẹ lagbaye gẹgẹ bi ajọ UNICEF ṣe kede rẹ.

Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ìtagbangba n'Ibadan

Iwadii fi han pe orilẹede Naijiria lo ṣe ipo keji lagbaye ninu awọn to ṣe igbọnsẹ sita gbangba.

Ikọ BBC ba awọn ara adugbo kan ni ilu Ibadan sọrọ lori ohun ti wọn n koju lojoojumọ pẹlu bi ayika wọn ṣe kun fun ẹgbin ti wọn si ni ọpọlọpọ igba ni awọn eeyan ti sọ adugbo wọn di aaye ti wọn n ṣe igbọnsẹ si.

Ẹwẹ, ijọba kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria ti n la awọn eeyan lọyẹ tori o n sakoba fun alafia awọn eniyan bẹẹ si ni wọn n gbẹ ṣalanga fun ṣiṣe gá ti wọn si n ṣe ipese omi ọfẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lóṣù mẹ́ta sẹ́yìn, mò ń wa ọkọ̀ taasín, ṣùgbọ́n wọ́n sọ mí di afọ́jú lọ́san gangan'

Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ìtagbangba l'Eko

Nilu Eko to jẹ ọkan gboogi lara awọn ilu ti ọrọ aje ti burẹkẹ, eeyan to le ni miliọnu mọkanlelogun lo n wa jijẹ mimu nibẹ.

Bi wọn ba n lọ ti wọn n bọ, ti wọn n jẹ ti wọn si n mu bakan naa, o di dandan ki wọn ṣe 'ga nile igbọnsẹ.

Lori ọrọ ṣiṣe igbọnsẹ yii ni ipenija wa eleyi to jẹ ohun to rọ mo ayajọ ọjọ ile igbọnsẹ ti ajọ isọkan agbaye gbe kalẹ lati tọpinpin ipenija ààyè igbọnsẹ jakejado agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Lọpọ agbegbe niluu Eko, awọn eeyan a maa saba ṣe ibẹrẹ nitagbangba ti eleyii a si ma mu ki ayika maa run to si le mu ki itankale aisan onigba ati awọn aisan miiran pọ lawujọ.

Lati le koju ipenija yii, ijọba ati awọn ọlọdani a maa pese aye igbọnsẹ fara ilu yala lọfẹ tabi ki wọn san owo perete lati le fi lo ààyè igbọnsẹ wọn yi.

Ladugbo Ọbalende fun apẹrẹ, ikọ wa pade arakunrin kan to n pese ile igbọnsẹ fawọn eeyan lowo perete lati le fi dẹkun iwa ṣiṣe ga nitagbangba nibẹ.

Taju Ekemode fẹyin ti nidii iṣẹ ọlọpaa to si ni oun ko fẹ ki a fi aworan oun han.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀

Nibi to kọ awọn ile igbọnsẹ si, o ni awọn kii fi igba tabi akoko da igba ti eeyan le fi lo ile igbọnsẹ.

Pẹlu bi o ti ṣe ni ile igbọnsẹ naa jẹ irọrun f'awọn to n gbe adugbo naa o ni awọn ṣi ni iṣoro pẹlu bi awọn eeyan ṣe n lo awọn ile igbọnsẹ rẹ.

''Pupọ ninu awọn to ba lo ile igbọnsẹ ni kii fiye si imọtoto ti wọn ba wa nibẹ. Bi wọn ko ba bi silẹẹlẹ, ẹlomiran a yagbẹ si gbogbo ilẹẹlẹ. Koda awọn mii a ma duro si ori awo igbọnsẹ dipo ki wọn jokoo.''

Image copyright Getty Images

Ekemode tun sọ fun ikọ BBC Yoruba pe ile igbọnsẹ tawọn ni ko to fawọn eeyan ti ko ribi ṣe ga.

Lọdun 2018, Minisita fọrọ ipese omi ni Naijiria Suleiman Adamu nibi ipade kan sọ pe ti orileede India ba fi le mori bọ kuro ni ipo ti wọn wa gẹgẹ bi orileede ti iwa ka maa ya'gbe nitagbangba ti peleke ju lọ, idojuti nla ni yoo jẹ fun Naijiria nitori awọn ni wọn yoo gba ipo India.

Adamu ṣalaye pe laarin ọdun mẹta pere ti wọn ṣagbekalẹ eto lati koju ipenija yii, India ti kọ ile igbọnsẹ ọgọrin miliọnu ti ida marundinlọgọrun ninu ida ọgọrun awọn eeyan India si ti ni imọ nipa lilo ile igbọnsẹ lọna to ba ode oni mu.

2019 ni India lawọn fẹ jawọ ninu iwa yiyagbe sita gbangba. 2019 ọhun lo si ti fẹ dopin yii.

Image copyright Getty Images, BBC

Njẹ Naijiria yoo ribi koju ipenija yiyagbe sita gbangba to gbode kan yii?

Tajudeen Ekemode ni idahun si ibeere yii ni ohun ko ro pe Naijiria le mori bọ ninu iwa yii pẹlu bi nnkan ti ṣe n lọ.

O ni kii ṣe nitoripe ijọba ko gbiyanju ṣugbọn bi ọrọ Yoruba to ni 'amukun ẹru rẹ wọ' ni ọrọ to wa nilẹ yi ti ṣe ri.

Ekemode ni 'bi a ba wo oke ti a ko wo isalẹ, ko lee yanju.'

''Koda ki ijọba pese awọn ile igbọnsẹ yii fawọn ara ilu, iṣoro ki awọn eeyan fẹ lo awọn ile igbọnsẹ yii naa wa ti wọn gbọdọ koju.''

''Bi ẹ ba ni ki ẹlomiran wa san owo lati fi tọ, wọn a ni owo naa ti pọ ju wi pe ṣebi itọ lasan lawọn fẹ tọ?''

O ni iru awọn eeyan bẹ ni wọn kii bikita lati yọdi sita gbangba lati tọ tabi yagbẹ.

Image copyright OTHER
Image copyright Getty Images

Koda ẹlomiran a ni ohun ma n gbadun bi atẹgun ṣe ma n fẹ si oun nidi nitagbangba ju ki ohun lọ lo ile igbọnsẹ.

Ekemode ni a fi ki a yi adisọkan awọn eeyan Naijiri pada lori lilo ile igbọnsẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àwa akódọ̀tí táà ń gba £1,500 lóṣù níbi sàn ju Sẹ́nétọ̀ lọ ní Nàìjíríà'