'Ìgbẹ́ tí wọ́n ń yà síbí kìí jẹ kí oníbàárà wá sọ́dọ̀ wa'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibadan: Wo àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ kí èèyàn máa gbọnsẹ̀ síbi tó bá wù ú

Iru ọjọ oni ni gbogbo ọdun ni ayajọ ọjọ igbọnsẹ lagbaye gẹgẹ bi ajọ UNICEF ṣe kede rẹ.

Iwadii fi han pe orilẹede Naijiria lo ṣe ipo keji lagbaye ninu awọn to ṣe igbọnsẹ sita gbangba.

Ikọ BBC ba awọn ara adugbo kan ni ilu Ibadan sọrọ lori ohun ti wọn n koju lojoojumọ pẹlu bi ayika wọn ṣe kun fun ẹgbin ti wọn si ni ọpọlọpọ igba ni awọn eeyan ti sọ adugbo wọn di aaye ti wọn n ṣe igbọnsẹ si.

Ẹwẹ, ijọba kaakiri awọn ipinlẹ Naijiria ti n la awọn eeyan lọyẹ tori o n sakoba fun alafia awọn eniyan.

Ijọba ti n ba awọn eeyan gbẹ ṣalanga fun ṣiṣe igá bẹẹ si ni ijọba n ṣe ipese omi ọfẹ.