EFCC: Akinwumi Sorinmade ni orúkọ tí Aroke ń lo ni ilé ìfowópamọ

Image copyright Laailasnews
Àkọlé àwòrán Ọdaran tó wà lẹ́wọ̀n tún wóke $100miílíọnu níta-EFCC

Olusegun Aroke tí àjọ tó n gbógun ti ìwà ìbàjẹ EFCC, jú ṣẹwọn ọdun mẹrinlẹ́logun ní ọgbà ẹwọn Kirikiri ní ìlú Eko ni wọ́n tún ń ṣe ìwadìí rẹ nitori pé oun ló tún wọké owó tó tó ọgọ́rùn mílíọnù naira laipẹ yìí.

Nínú ọgba ẹwọn lo ti ń ni ajọsẹpọ pẹ̀lú àwọn aráa rẹ̀ to kù nita pàápà jùlọ àwọn ti àjọ EFCC ń ṣewadiìí wọn fún kíkó owó ìlú pamọ lọ́nà àìtọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lóṣù mẹ́ta sẹ́yìn, mò ń wa ọkọ̀ taasín, ṣùgbọ́n wọ́n sọ mí di afọ́jú lọ́san gangan'

Bawo ní Aroke ṣe tún le hùwà ọdaran láti inú ọgbà Ẹwọn

Ajọ EFCC sàlàyé pé ìwádìí fi han pé lòdi si òfin to gbe ọgbà ẹwọn ró o ní ànfani sí ẹ̀rọ ayelujara àti ẹrọ iléwọ nínú ọgbà ẹwọn to yẹ ti maa ṣẹwọn rẹ.

Wọn ni òun to tún wá yani lẹ́nu jùlọ ni pe Aroke lọ fun ìtọjú ara rẹ ni ilé ìwòsàn àwọn ọlọpàá ní Falomo nilú Eko fun àisan kan.

Láti ile ìwòsàn yìí ni o ti maa ń ló si ilé ìtura nibi tí o ti n ri ìyàwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjí, nígba miran a tún maa lọ fún awọn ayẹyẹ to ba ni.

Bakan náà lo n lo orúkọ ti kìí jẹ Akinwumi Sorinmade, lati sí àpò ikówópamọ meji ni First Bank àti Guaratee Trust Bank (GTB), o ra oun ini si Fountain Spring Estate ni Lekki lọdun 2018 ni mílíọnù mejilélógun àti Lexus RX 350 fún iyawo rẹ̀ Maria Jennifer Aroke.

Ọdaran náà ni asẹ ǹkan ti ìyàwo rẹ̀ fi n gbowo ni Banki lọ́wọ́ nínú ọgbà ẹwọn to n lo lati rà tàbi ta bo ṣe wù ú nínú ọgbà ẹwọn to wá.

Wọn tun sàlàye pé lasìkò ti ìgbẹ́jọ rẹ̀ ń lọ lọdun 2015 ni Aroke ra ilé oni yàra mẹrin ni Plot 12, Deji Fadoju òpópònà, Megamounds Estate Lekki County Homes , Lekki ní mílíọnù N48.

Ọ̀daràn tó wà lẹ́wọ̀n tún wọ́'ke $100miílíọnu - EFCC

Olusegun Aroke Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán Ọdaran tó wà lẹ́wọ̀n tún wóke $100miílíọnu níta-EFCC

Ajọ to ń gbógun ti ìwà jẹgúdújẹra ní orílẹ̀èdè Naijiria (EFCC) ní àwọn tí rí àsírí Hope Olusegun Aroke tí wọ́n jù sí ẹwọ̀n ọdún mẹ́rìnlélógun fún ìwà ọdàràn gbájuẹ̀ orí ayélujára pé o tún ni ibánisọrọ kíkún pẹ̀lú àwọn ọdàran mìíràn ti wọ́n si n ṣe ìwádiìí wọ́n lọ́wọ́.

EFCC ni àwọn ń ṣe ìwádìí wọ́n fún oníruuru ìwà ọdaran ori ayelujára àti kíko owó pamọ lọ́nà àìtọ́, àti pé ìwádìí fi han pé Olusegun Aroke lo ṣe agbódegbà fún olé ori ayelujara tó tó ọgọ́rún kan mílìọnù dọ́là bi o ṣe n ṣẹ̀wọ̀n rẹ̀ lọ́wọ́.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀

Adajọ Lateefa Okunnu ti ilé ẹjọ giga ìlú Eko to wà ni Ikéja lo dájọ rẹ ninu osù kini ọdun 2016 láti ṣẹ̀wọ̀n ọdun mẹ́rìlélógun fun gbájuẹ̀ ori ayélujára lórí owó mílíọnù márundinlọ́gbọ̀n.

Akẹ́kọ̀ọ́ fasiti kan ni Malaysia ni Olusegun ki wọ́n tó mú u, ṣùgbọ́n kò fi ìgbà kankan simi iṣẹ́ gbájuẹ, lẹ́wọ́n gan ko dáduró láti tẹsíwájú iṣẹ́ gbájúẹ̀ rẹ to n ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lóṣù mẹ́ta sẹ́yìn, mò ń wa ọkọ̀ taasín, ṣùgbọ́n wọ́n sọ mí di afọ́jú lọ́san gangan'