#InternationalMensDay: Kí láwọn èèyàn fi kan sára s'áwọn ọkùnrin láyàjọ́ ọkùnrin lágbayé

Aworan awọn ọkunrin oṣere

Ki a to bẹrẹ ọrọ nipa ayajọ awọn ọkunrin lagbaye o tọ ki a jẹwọ pe nileeṣẹ wa lonii gan, kii ṣe gbogbo awọn obinrin to wa nibi lo ranti ki awa ọkunrin.

O tọ bakanna ki a tun sọ pe awọn ọkunrin gaan ko ranti pe wọn ya ọjọ yii sọtọ f'awọn, abi ẹ o ri nkan bii?

Bi awọn ko ti ṣe ranti la ba ni ki a kan si oju opo ayelujara lati wo boya awọn eeyan n sọrọ nipa ayajọ yii ati pe ki gaan ni ohun to rọ mọ.

Ki a to bẹrẹ si ni ṣafihan ohun ti wọn sọ, o ṣe pataki lati la ara wa lọye bi ọjọ yi ti ṣe waye

Lọdun 1992 ni wọn ṣe ifilọlẹ ọjọ yi lati pe akiyesi si awọn ohun to nii ṣe pẹlu ipa tawọn ọkunrin n ko lagbaye.

Image copyright INSTAGRAM
Àkọlé àwòrán Gbajúgbajà Òsèré Yoruba, Kunle Afod ti kópa nínú fíímù bíi Nkan agba, Odi ade, Ofin kokanla, Pitan ati Orindola.

Yatọ si awọn idi wọnyii, ọjọ naa ti wọn ṣagbekalẹ rẹ lori opo mẹfa, a maa ni akori orisirisi ti o nii ṣe pẹlu igbe alaafia f'awọn ọkunrin ati kikọ awọn ọdọkunrin ni iwa to yẹ lawujọ.

Ki lawọn eeyan n sọ nipa rẹ loju opo Twitter?

#InternationalMensDay ni awọn eeyan fi n p'akiyesi si ọjọ yii loju opo Twitter .

Labẹ hashtag yii, wọn n sọ nipa awọn ipenija to n ba awọn ọkunrin ti awọn miiran si n kan sara si ipa tawọn ọkunrin n ko lawujọ .

Arakunrin kan tilẹ sọ nipa iṣoro ti oun n koju eleyi to mu ki o fẹ gba ẹmi ara rẹ ni nnkan bi ọdun meloo kan sẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics