Irú kí leyi,iná jó òkú méjìlá mọ inú ílé ìgbókúpamọ́sí OAU

Lagos Fire Service: Ẹ má se tan àbẹ́là lórí ike tàbí pákó Image copyright Getty Images

Ẹni ti ku ti nisinmi ni Yoruba a ma wi,ṣugbọn kini ka ti ṣe pe ti awọn oku mejila kan ti ina jo mọ aaye igbokupamọsi.

Iṣẹl yi waye ni oru ọjọ Iṣẹgun nigba ti ina kan ṣadede ṣẹyọ ni aaye igbokupamọ si ni ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ti fasiti Obafemi Awolowo ni ilu Ile Ife.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Osun lo fidi ọrọ yi mulẹ fun ikọ BBC Yoruba.

Folashade Odoro ṣalaye pe ko si ẹmi kankan to nuu ninu iṣẹlẹ naa ati pe aaye ikokupamọ si ni ijamba ina naa ṣakoba fun.

O tẹsiwaju pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadi lori ohun to fa ina naa.

Ninu ọrọ ti wọn ta ri gbọ lati inu iwe Iroyin Naijiria,Punch,alukoro fasiti Obafemi Awolowo Abiodun Olanrewaju ninu sọ ninu atẹjade kan pe oku mejilelọgọrun lo wa nibi aye ikokupamọsi.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, o ni nnkan bi ago mẹta oru ọjọ Iṣẹgun ni ina naa bẹrẹ.

''Ẹka fasiti naa ti ṣe eto lati fi ọrọ yi to awọn to loku ninu aye ikokupamọ si leti.''

Olanrewaju ni ọga agba fasiti naa Ọjọgbọn Eyitope Ogunbodede ti ṣe agbekalẹ igbimọ lẹni mẹta ti yoo se iwadi ohun to fa ina naa

Related Topics