Kogi Election: Kí ló mú àwọn jàndùkú dáná sun Aṣáájú obìnrìn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọlé ?

Aworan obinrin to jonqa mọle Image copyright OTHER

Awọn afunrasi janduku kan ti dana sun aṣaju awọn obinrin ẹgbẹ oṣelu PDP kan mọ inu ile nipinlẹ Kogi.

Atẹjade kan lati ọdọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi sọ pe Acheju Abuh lorukọ obinrin ti o kagbako iku ojiji ninu ile rẹ ni Ochadamu,eyi to wa ni ijọba ibilẹ Ofu, nipinlẹ Kogi.

Iṣẹlẹ naa waye lẹyin idibo gomina ni ọjọ Àbámẹ́ta tó kọjá nipinlẹ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe edeaiyede waye laarin okunrin kan ti orukọ rẹ njẹ Awolu Zekeri, eni ọdun 35 to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ati Gowon Simeon to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni agbegbe Ochadamu.

Nigbati aawọ yi waye, Gowon Simeon fi ọbẹ gun Awolu Zekeri ni itan, eyi to fa iku Zekeri lona ile iwosan.

Iṣẹlẹ aburu yi lo fa ibinu awọn ọdọ adugbo, eyi to mu ki wọn lọ si ile Simeon Abuh, eni to jẹ ẹgbọn fun Gowon, to ṣe ijamba naa.

Nibe ni wọn ti dana sun ilẹ rẹ pẹlu arabinrin Salome Abuh to wa ninu ile lasiko naa. Eni ọdun ọgọta ni Salome Abuh.

Yatọ si ile yi,Ile mẹta miran ni awọn ọdọ naa tun dana sun.

Oku arabinrin naa ni a gbọ pe wọn ti gbe lo si ile igbokupamọsi to wa ni ile ẹko iwosan ẹkọṣẹ Ayingba fun ayẹwo.

Awọn ọlọpaa ti ko awọn ẹṣọ si agbegbe naa lati dẹkun rogbodiyan to le waye nitori iṣẹlẹ naa.