'Lóṣù mẹ́ta sẹ́yìn, mò ń wa ọkọ̀ taasín, ṣùgbọ́n wọ́n sọ mí di afọ́jú lọ́san gangan'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Tomi Waziri: Kí n tó gbé fóònù lé wọn lọ́wọ́, wọ́n ti fi ìbọn fọ́ mi lójú

Nigba ti BBC Yoruba ṣe ibẹwo si ile ti Waziri ati iya rẹ n gbe, ọrọ naa kọja afẹnusọ.

Iya Waziri kẹnu bọ ọrọ pe lẹyin Ọlọhun, ọmọ yii nikan lo ku fun oun.

Bawo lọrọ naa ṣe ṣẹlẹ gan? Adigunjalẹ̀ fìbọn fọ́ ojú ọmọ tó fẹ́ lọ sìnrú ìlú nílùú Èkó

'Olùkọ́ kan tilẹ̀ sọ fún un pé "ẹlẹ́sẹ̀ kan ni ẹ́, oò ní 'le ...'

'Iṣẹ́ akólẹ̀ tí mò ń ṣe níbí, mi ò lè ṣe é láí lái ní Nàìjíríà tórí...'

Waziri lo n gbọ jijẹ mimu ninu ile ṣùgbọ́n "igba ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ ko si nkan to le da ṣe funra rẹ".

"Kò s'ólùrànlọ́wọ́ míì lẹ́yìn Ọlọ́run àtòun yìí nìkan kó tó di pe ojú rẹ lọ". Iya Waziri sọ ẹdun ọkan rẹ fun akọroyin BBC Yoruba.

O ni "ó dàbíi ká gbé ẹru wúwo léèeyàn lórí ni".

Waziri funrarẹ ni "bí wọ́n ṣe yìnbọn lù mí lójú gbàrà, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí pé ṣe bó ṣe máa rí nìyìí".