Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé àìsàn òtútù àyà kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú òtútù?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá òtútù àyà

Ọpọ asọdun lo maa n waye nipa aisan kan ta n pe ni otutu aya eyi ti oloyinbo n pe ni Pneumonia.

Koda, aisan yii wọpọ ni Naijiria, paapa laarin awọn ọmọde, ti ajọ Unicef si ti kede pe orilẹede Naijiria wa lara awọn ti aisan naa ti wọpọ lagbaye.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Onisegun oyinbo kan, Dokita Afeez Oladele ni aisan otutu aya ko ni ohunkohun se pẹlu otutu rara nitori eeyan lee sun si ori ilẹ lasan tabi si aya si ẹrọ amuletutu lai wọ asọ, ti onitọun ko si ni ni otutu aya rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn kokoro kan ti a ko lee fi oju ri lo n fa aisan naa, ti a si lee ko awọn kokoro kekeke naa latinu afẹfẹ buruku, eefin, eedu, tabi ka lo ife ati ifọyin ẹni to ba ni aisan naa.

O wa gba awọn obi nimọran lati maa tete gbe awọn ọmọde ti wọn ba kẹẹfin pe o n hu ikọ lọ sile iwosan fun itọju, ki aisan naa to bọwọ sori.