Ìtàn Mánigbàgbé: Àáró tó yẹ kí Lisabi gbà, ló fi bẹ ọ̀wẹ̀ láti kọlu Ìlàrí Ọlọyọ fún ìdáǹdè Ẹ́gbá

Ere Lisabi Agbongbo Akala Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ìtàn Mánigbàgbé: Àáró tó yẹ kí Lisabi gbà, ló fi bẹ ọ̀wẹ̀ láti kọlu Ìlàrí Ọlọyọ fún ìdáǹdè Ẹ́gbá

Abẹokuta jẹ ilu to gbajumọ nilẹ Yoruba, a si mọ ilu naa bii ilu Ẹgba, ilu ta tẹdo labẹ Olumọ, ti wọn si maa n ki awọn ọmọ Ẹgba ni ọmọ Lisabi.

Ko si bii eeyan yoo se sọ itan Ẹgba, ti a ko ni darukọ Lisabi Agbongbo Akala.

Ẹni ti itan sọ fun wa pe o ko ipa ribiribi nidi idagbasoke, alaafia ati ilọsiwaju awọn Ẹgba ati ilu Abẹokuta, bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe oun lo da ilu naa silẹ, gẹgẹ bi awọn eeyan kan se lero

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi si ree ti wọn se ya ọjọ kan sọtọ nilu Abẹokuta lati maa fi ṣe iranti akọni baba Ẹgba to ti lọ naa, ti wọn n pe ni Lisabi Day.

Ọjọ Kẹrinla, osu Kẹta, ọdọọdun si ni ayajọ Lasabi naa maa n waye nilu Abẹokuta.

Pataki akọni to ti dara ilẹ yii lo mu ki BBC Yoruba se fẹ ka mọ itan igbe aye rẹ gẹgẹ bi a se rii ka loju opo ayelujara nitori bi onirese rẹ ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ, ko lee parun.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ọjọ Kẹrinla, osu Kẹta, ọdọọdun si ni ayajọ Lasabi naa maa n waye nilu Abẹokuta.

Itan igbe aye Lisabi Agbongbo Akala:

 • Bi o tilẹ jẹ pe ko si akọsilẹ fun akoko ti Lisabi Agbongbo Akala de ile aye, tabi orukọ awọn obi rẹ, amọ a ri i ka pe ọmọ bibi adugbo Itoku ni, to si n gbe adugbo Igbẹhin nigba to dagba tan.
 • Lisabi di ilumọọka ni aarin ọdun 1775 si 1780 nigba to ja fita fita lati gba ilu Abẹokuta silẹ loko ẹru Ọlọyọ ti ilu Ọyọ nigba naa, ẹni to n gba isakọlẹ lọwọ awọn ọmọ Ẹgba lasiko naa.
 • Lai mọ pe ọjọ ija kan n bọ lọna, Lisabi se idasilẹ ẹgbẹ awọn ọkunrin kan, eyi to dabi ẹgbẹ alafọwọsowọpọ silẹ
 • Egbẹ yii ni ti wọn ti n pe ara wọn si oko aaro sise, nibi ti wọn yoo ti maa ran ara wọn lọwọ ni oko wọn

Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà

Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa ‘Ajala Travels’?

Afárá odo ọya keji :Ta ni yóò parí rẹ?

Wole Soyinka rèé láti kékeré

 • Lasiko naa, Ọlọyọ, ti a n pe ni Alaafin lasiko yii, ti fi awọn Ajẹlẹ ati Ilari sọwọ silu Ẹgba lati maa gba isakọlẹ loore koore lọwọ wọn, ki wọn si maa fi isakọlẹ naa ransẹ si Ọlọyọ
 • Awọn Ilari yii n mu ki aye le fun awọn Ẹgba nitori aye familete ki n tutọ ti wọn n jẹ laarin awọn Ẹgba.
 • Wọn a ko ire oko awọn Ẹgba bo ṣe wu wọn, ti wọn si tun n fẹ wọn laya pẹlu laisi ẹni ti yoo yẹ awọn Ilari yii lọwọ wo, nitori aye Ọba ni wọn njẹ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkogosi-Ekiti: Ilu ti omi tutu ti dapọ mọ gbigbona
 • Awọn isẹlẹ yii ko dun mọ Lisabi ati awọn ọmọ ẹgbẹ aaro rẹ ninu, ti wọn si maa n jẹ awọn iya ti awọn Ilari fi n jẹ wọn lẹnu lojoojumọ.
 • Koda, ọba, awọn ijoye ati awọn aṣaaju ilẹ Ẹgba ti gba kamu, ti wọn ko si mọ ohun ti wọn lee ṣe mọ lati gba ara wọn silẹ lọwọ awọn Ilari Ọlọyọ.
 • Ninu ẹgbẹ aaro ti Laṣabi ati awọn ẹgbẹ rẹ n se, Lisabi maa n sisẹ takuntakun lati ro oko awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ to ba kan lati gba aaro, ti oun funra ara rẹ ko si gba aaro kankan lọwọ awọn ọrẹ rẹ fun ọjọ pipẹ.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele
 • Yoruba ni ma fi oko mi sọna, ọjọ kan ṣoso laa kọ, nigba to di ọjọ kan, aaro kan Lisabi lẹyin ti gbogbo awọn ọrẹ rẹ ti gba tan.
 • Amọ dipo ki Lisabi mu awọn ọrẹ rẹ lọ si oko rẹ fun aaro, ohun to sọ fun wọn ni pe ọna ti awọn yoo gba gba ilu Ẹgba silẹ lo kan oun, aaro ti wọn yoo si ba oun gba ni kikọju ogun si awọn ilari Ọlọyọ.
 • Idi ree ti Lisabi ati awọn ẹmẹwaa rẹ pa orukọ ẹgbẹ wọn pada si Ẹgbẹ Ologun, ti wọn si n gbe awọn ohun ija oloro lorisirisi rin, bẹẹ ni wọn n gbaradi bii ologun lati kọ iya fun awọn ọmọ Ẹgba.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde
 • Nigba to di ọjọ kan, Lisabi kọlu awọn Ilari to wa ni adugbo to n gbe ni Igbẹyin.
 • Awọn ọmọ ẹgbẹ Ologun rẹ, gẹgẹ bii ajọsọ wọn, naa kọlu awọn Ajẹlẹ ati Ilari to n gbe ni adugbo ikọọkan wọn, ti gbogbo wọn si fi iya nla jẹ awọn iriju Ọlọyọ ọhun
 • Onisẹ kan Ọlọyọ lara nilu Ọyọ pe awọn Ẹgba ti siwọ lu imi, wọn ti tẹ ofin oun loju mọlẹ, ti inu si bi i gidigidi pe wọn fi ori ade wọlẹ bii eyi, ẹni to ba si ri ọba fin, ni ọba n pa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'
 • Ọlọyọ ransẹ pada silu Ẹgba pe ki wọn lọ jẹ wọn run amọ gudugudu awọn ọmọ Ẹgba Ologun Lisabi ko fi igba kankan tura silẹ,
 • Koda ajẹkun iya ni awọn ọmọ ogun Ọyọ tun jẹ nilu Ẹgba lati ọwọ awọn Lisabi, ti wọn si gba itusilẹ fun awọn Ẹgba lọwọ igbekun Ọlọyọ tilu Ọyọ.
 • Lati igba yii wa ni awọn Ẹgba ko ti fi isakọlẹ ransẹ mọ si Ọlọyọ, ti wọn si gba idande lọwọ iwa imunisin Ọlọyọ.

Kí lo fẹ́ mọ̀ nípa D.O Fágúnwà?

Ẹ̀ wo bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú etí òkun ṣe ń ṣiṣẹ́ l'Eko

O ṣójú mí kóró bí wọ́n ṣé fí àdó olóró pa Dele Giwa lọdún 1986- Soyinka

Ṣòwòrẹ́, káàbọ̀ ságbo àwa tí wọ́n ti fẹ̀sùn kàn rí -Soyinka

Ọgbọn ti itan igbe aye Lisabi Agbongbo Akala:

 • O kọ wa pe agbajọ ọwọ la fi n sọya, ajeje ọwọ kan ko gbe ẹru dori
 • Itan naa tun fi ye wa pe ko si ogun ti a ko lee sẹ ninu irẹpọ
 • A tun ri ọgbọn kọ pe a gbọdọ nifẹ ilu wa gẹgẹ bi ara wa
 • Gbogbo alagbara to n jẹ gaba lori aye wa la lee sẹgun wọn pẹlu irẹpọ ati isọkan.

O yẹ ki gbogbo wa sa ipa wa lati ran ilu wa lọwọ, ka si dide lati ja fun alaafia rẹ nibikibi.