Nollywood: Toyin Abraham ń ta àgbo, Wumi Toriola, Ronke oshodi Oke ń ta ìpara ìbóra

Ronke Oshodi Oke ati Mercy Aigbe

Ọpọ oju to n pawo ninu awọn fiimu agbelewo wa lo jẹ ilumọọka fun ọpọ eeyan lorilẹede Naijiria.

Koda, ọpọ eeyan si maa n fi oju ipa ti wọn n ko ninu ere se odiwọn igbe aye wọn loju aye nitori awọn miran to n ko ipa olowo ni wọn maa n fi oju olowo wo.

Sugbọn awọn osere yii lo maa n kigbe lọpọ igba pe okiki nikan ni awọn ni, awọn ko fi bẹẹ ri taje se, idi si niyi ti ọpọ awọn osere naa se mu ọna mii pọn lati ni owo lọwọ nitori ọna kan ko wọ ọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi si ni awọn osere tiata lobinrin to mu okoowo miran mọ isẹ tiata, ati irufẹ okoowo ti wọn n se:

Wunmi Toriola: Okoowo ipara to n bora lo mu mọ isẹ tiata

Ọdọmọde osere tiata ni Wunmi Toriola to sẹsẹ bi ọmọkunrin kan laipẹ yii, ti orukọ rẹ n jẹ Zion.

Image copyright Instagram/teamwumitoriola

Wunmi lo tun mu isẹ pipo ipara ati ọsẹ iwẹ to n bora mọ isẹ tiata lati ri taje se, to si fi orukọ ara rẹ pe idamọ eroja ipara to n ta.

Ti eeyan ba si de oju opo Instagram rẹ, Wumi ko fi bo rara nipa okoowo to yan laayo, to si n ke si iruwa, ogiri wa lati wa ra ohun to n ta.

Mide Martins Abiodun: Isẹ asọ tita lo tun mu lọkunkundun lẹyin ere sinima

Ẹlomiran to tun mu okoowo mii mọ isẹ tiata ni Mide Martins aya Afeez Owo Abiọdun, ti awọ̀n mejeeji dijọ jẹ gbajumọ nidi isẹ tiata.

Image copyright Instagram/zanzeespabeautynstyle

Iya alasọ tun ni a ba maa pe Mide lẹ́yin pe o jẹ́ osere tiata ti aye n gba tiẹ nitori ojoojumọ lo n polowo awọn asọ to n ta lori ayelujara.

Koda, mawọtana ni awọn aworan rẹ to n gbe sori ayelujara lojoojumọ, to si dabi ẹnipe o ni ẹnikeji ti wọn jọ da okoowo naa pọ.

Toyin Abraham: Egboogi fun onibisi ni oun yan laayo

Oju to pawo ni Toyin Abraham ninu awọ̀n fiimu oloyinbo ati ni ede Yoruba, to si jẹ aayo ọpọ eeyan .

Image copyright Instagram/toyin_abraham

Laipẹ yii ni osere tiata naa bi ọmọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Ire, ti ọpọ eeyan si n ki ku oriire.

Lẹyin to bimọ tan lo wa sọ asiri ọna to gba bi ọmọ eyi to ni ko sẹyin egboogi ibilẹ kan to pe ni agbo

Lati igba naa si lo ti n polowo egboogi yii fun awọ̀n eeyan to n woju Ọlọrun fun ọmọ tiwọn pe ki wọn wa ra agbo naa, ki lọ ayọ lee sọ ninu wọn.

Egboogi yii si lo ti se nilana ti oloyinbo sinu apo kan, to fi sọ orukọ ara rẹ.

Ronke Oshodi Oke: Katakara eroja ipara ati ọsẹ ibora ati atọkun eto lo mu mọ isẹ tiata

Ronke Ojo Anthony ti a tun mọ si Ronke Oshodi Oke ko fi okoowo to n se lẹyin isẹ tiata se asiri rara nitori ojoojumọ lo n polowo ohun to n ta lori ayelujara.

Image copyright Instagram/ronkeoshodioke

Koda, ọna kan ko wọja ni a ba maa pe Oshodi Oke nitori kii se okoowo kan lo mu mọ ere itage, bo se n ta ipara ati ọsẹ ibora, naa lo tun n se atọkun eto.

Yatọ si eyi, Ronke tun maa n gba isẹ alaga iduro nibi ayẹyẹ igbeyawo, gbogbo awọn okoowo naa si lo n mu ki Oshodi Oke ri taje se.

Mercy Aigbe: Asọ Ẹbi tita ni na tawọn mu pọn lẹyin fiimu sise

Mercy Aigbe ti oun naa jẹ gbajumọ osere ko kawọ gbera rara nigba ti awọn akẹẹgbẹ rẹ n wa owo.

Image copyright Instagram/asoebimercy

Bi awọn akẹẹgbẹ rẹ se mu na kan pọn, ni oun naa gba ọna keji yọ, to si lọ si sọọbu asọ tita.

Asọ oloyinbo ni mama Juwọn kọkọ n ta, to si si sọọbu kaakiri to fi mọ ilu Eko ati Ibadan.

Amọ ọgbọn okoowo Mercy ti sun siwaju bayii tori o ti mu asọ ẹbi tita mọ ọja rẹ, bo si se n ta asọ fun awọn oniyawo, lo n ta tawọn ọljọ ibi ati tawọn oloku agba.

Dayo Amusa: Ohun didun ni o fi n gbe awo orin jade

Isẹ ori ran mi ni mo n se ni ọrọ Temidayo Amusa nitori ko ta igba abi awo rara, orin lo n mu kọ lẹyin isẹ tiata.

Laipẹ yii si ni Dayo gbe awo orin tuntun kan jade eyit o milẹ titi, to si pe akọle rẹ ni Mosorire.

Yika awọn oju opo ayelujara si ni wọn ti n k awo orin naa, to fi mọ awọn ori tẹlifisan ati redio.

Lizzy Anjorin: Bo se n polowo okoowo asọ ninu sọọbu rẹ lo tun n ta ilẹ ati ile

Ọna lati ri ọwọ mu lọ sẹnu lẹyin isẹ ere sise lo mu ki ilumọọka osere tiata lobinrin, Lizzy Anjorin fi tun si sọọbu asọ.

Image copyright Instagram/Lizzy Anjorin

Ipolowo ọja asọ yii ni Lizzy kii fi sere rara lori ayelujara, bo si se n jo lati polowo fun awọn onibara, naa lo n kọrin lati fa oju wọn mọra.

Tẹ ba wo Lizzy lasiko to ba n polowo ọja rẹ, ẹ mọ pe isẹ aje le.

Lọwọlọwọ bayii, Lizzy tun ti mu okoowo ilẹ ati ile tita mọ katakara lati ri taje se.