Revolution Now: Sowore, Bakare gbé ọga DSS lọ sílé ẹjọ́, wọn ń bèèrè fún bílíọ̀nù kan náírà

Omoyele Ṣowore Image copyright Facebook/Omoyele Sowore

Omoyele Ṣowore ati Olawale Bakare ti wọn wa latimọle ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti n mugbe bọnu bayii, ti awọn mejeeji si ti gbe ọga DSS, Yusuf Bichi ati ọga ẹka eto idajọ ni Naijiria, Ọgbẹni Abubakar Malami lọ sile ẹjọ.

Ṣowore ati Bakare gbe awọn mejeeji lọ si ile ẹjọ giga l'Abuja, bakan naa ni wọn beere fun ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira fun ẹni kọọkan wọn fun inira ti ajọ DSS fun wọn lati igba ti wọn ti wa latimọle.

Wọn ni owo yii tun wa fun bi ajọ DSS ti fi ẹtọ wọn dun wọn lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ idasilẹ wọn latimọle, ti wọn ko si jẹ kawọn lanfaani si eto ilera, ati ẹtọ awọn lati rin lọ si ibikibi to ba wu awọn.

Wọn fikun ọrọ wọn pe mimu ti ajọ DSS mawọn ati iya ti wọn fi jẹ awọn niluu Eko lọjọ keji oṣu kẹjọ ati niluu Oṣogbo lọjọ karun un oṣu kẹjọ tako ẹtọ ọmọniyan awọn.

Awọn agbẹjọro wọn, Femi Falana to pe ẹjọ naa lorukọ Ṣowore ati Bakare, tun ni ọga ajọ DSS ati ti ẹka eto idajọ tun tapa sofin orilẹede Naijiria gẹgẹ bi o ti wa ni akọsilẹ ninu iwe ofin.

Ọjọ kẹfa oṣu kọkanla nile ẹjọ ti paṣẹ pe ki ajọ DSS fi Ṣowore ati Bakare silẹ lahamọ, ṣugbọn DSS kọ eti ikun si aṣẹ ile ẹjọ.