Muhammadu Buhari: APC ẹ ṣọ́ra, ẹgbẹ́ kò gbọdọ̀ túká lẹ́yìn ìsàkóso mi

Muhammadu Buhari Image copyright Instagram/Prof Yemi Osinbajo

Ko si ohun to jọọ rara! Aarẹ Muhammadu Buhari soju abẹ niko lori iroyin kan to n tan kalẹ pe aarẹ n gbero lati lọ fun saa kẹta, ti saa keji rẹ ba pari.

Aarẹ Buhari sọ pe, oun ko ni ṣe aṣiṣe lati gbegba ibo aarẹ fun saa kẹta gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Buhari sọrọ yii mimọ nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ osẹlu APC to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti.

Aarẹ Buhari ni yatọ si ọjọ ori oun, o ni oun ti bura pẹlu iwe mimọ pe oun ko ni ṣe ohun kohun to lodi si iwe ofin orilẹede Naijiria.

Buhari ni saa meji ti iwe ofin ilẹ Naijiria la kalẹ fun ipo aarẹ naa loun yoo ṣe.

Aarẹ wa kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu APC nibi ipade ọhun pe ẹgbẹ APC ko gbọdọ tuka lẹyin ti oun ba pari saa keji oun tan.

Image copyright Facebook/Femi Adesina

Buhari rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati ṣa ipa wọn, ki wọn si rii pe APC lẹgbẹ to siwaju ninu awọn ẹgbẹ oṣelu to wa lẹkun wọn.

Aarẹ Buhari ni iwe itan yoo sọ itan rere nipa awọn ọmọ ẹgbẹ APC lọjọ iwaju, ti onikaluku ba gbiyanju lati ri pe APC fẹsẹ mulẹ lẹkun wọn.