Omí pọ̀ ju ọkà lọ fún Unai Emery, ìfìdírẹ̀mi mí ló bade fún lọ́wọ́ Frankfurt

Unai Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Omí pọ̀ ju ọkà lọ fún Unai Emery, ìfìdírẹ̀mi mí ló bade fún lọ́wọ́ Frankfurt

Ninu atẹjade ti Arsenal fi soju opo twitter wọn ni wọn ti kede ipinnu wọn bayii.

Wọn ni àwọn gbe igbesẹ yii lataari gbogbo ijakulẹ ti Unai emery n ri paapaa lori idije awọn bọọlu ti Arsenal n gba ti to gẹ.

Josh Kroenke lasiko to n sọrọ lorukọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Kroenke Sports and Entertainment so pe:

"A dupẹ lọwọ Unai ati awọn akẹgbẹ rẹ pupọ nitori pe wọn gbiyanju lati da ogo Arsenal pada de ipele to yẹ ti a beere fun.

A gbadura arinna kore fun wọn bi wọn ti n lọ."

Ẹgbe Arsenal ti le Unai Emery leyin osu mejilelogun, to gba ise.

Amo, Freddie Ljungberg to je igbakeji akonimoogba ni yoo ma sakoso fun igba yii naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Kò sí bóyá mọ́, ìgbà tí Arsenal yóò lè Unai Emery láwọn èèyàn n retí

Ọrọ boya iṣẹ yoo bọ lọwọ akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal Unai Emery tun fidi rinlẹ si lọkan awọn onwoye pẹlu bi ikọ rẹ ṣe fidirẹmi lọwọ Frankfurt ninu idije Europa League.

Ayo meji si odo ni ẹgbẹ agbabọọlu naa fi gbewuro soju ikọ Unai Emery.

Image copyright BBC Sport
Àkọlé àwòrán Omí pọ̀ ju ọkà lọ fún Unai Emery, ìfìdírẹ̀mi mí ló bade fún lọ́wọ́ Frankfurt

Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba sẹyin, eyi ni yoo jẹ igba kẹje ti wọn yoo pade ijakulẹ.

Lẹnu lọọlọ yi, ẹnu ti n kun Unai Emery ti ọpọ si ti n reti igba ti wọn yoo fọwọ osi juwe ile fun un.

Image copyright EPA

Laipẹ yi ni ẹgbẹ Arsenal lawọn ti n fimu-finlẹ si ẹni ti wọn yoo fi paarọ rẹ ni eyi ti ireti si wa pe o ṣeeṣe ko jẹ akọnimọọgba ẹgbẹ Wolves, Nuno Espirito ni yoo gba ipo rẹ.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Omí pọ̀ ju ọkà lọ fún Unai Emery, ìfìdírẹ̀mi mí ló bade fún lọ́wọ́ Frankfurt

Niṣe ni igbe ọọbi gba nu awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa lẹyin ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Frankfurt ti oju opo Twitter si kun fun ikunsinu lori bi o ti ṣe n tukọ ẹgbẹ naa.

Ọpọlọpọ gba pe iṣẹ rẹ ko dara to ni ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe n ri ijakulẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYorùbá tone mark: Fífi àmì ohùn sí orí ọ̀rọ̀ Yorùbá ṣe pàtàkì

Related Topics