University of Transportation Daura: Nǹkan mẹ́wàá tó yẹ ní mímọ̀ nípa fásitì ẹ̀kọ́ ìrìnnà

Aworan Aaarẹ Buhari nibi ifilọlẹ fasiti Daura Image copyright Buharisallau1
Àkọlé àwòrán Nǹkan mẹ́wàá tó yẹ ní mímọ̀ nípa fásitì ẹ̀kọ́ ìrìnnà

Aarẹ Muhammadu Buhari ti lọ ṣe ifilọlẹ fasiti onimọ nipa irinna akọkọ iru rẹ ni Naijiria.

Ni ilu aarẹ, Daura nipinlẹ Katsina ni ariwa Naijria ni wọn yoo kọ ọgba ile ẹkọ naa si.

Wọn yi lawọn nkan mẹwaa to yẹ ni mimọ nipa fasiti tuntun yi :

  • Ni oṣu Kẹwaa, ọdun 2018 ni ijọba apapọ buwọlu owo ti wọn yoo fi kọ ile ẹkọ yi ni ibamu pẹlu ilana ajọ to n ṣakoso fasiti ni Naijiria (NUC)
  • Fasiti yi yoo gbajumọ iwadii ati idagbasoke ohun amuṣagbara ti yoo mu idagbasoke ba ẹka irinna ni Naijiria.
  • Yatọ si ọgba fasiti naa ti yoo wa ni Daura, wọn yoo tun ṣe gabekalẹ fasiti miran si ipinlẹ Rivers tii ṣe ilu Minisita fetro irinna Naijiria lọwọlọwọ Rotimi Amaechi.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA
  • Gẹgẹ bi ohun ti Minisita Amaechi sọ, aadọta miliọnu dọla tii ṣe biliọnu mejidinlogun Naira ni wọn yoo na lori kikọ fasiti yi.
  • Ile iṣẹ agbaṣe ilẹ China, China Civil and Construction Company (CCECC) ni yoo kọ fasiti yi.
  • Amaechi ni Eredi fasiti yi ni ki wọn le ṣagbekalẹ awọn onimọ lẹka irinna Naijiria.

Dino ní ìyàwó ni Adeyemi jẹ́ f'óun lágbo òṣèlú, Adeyemi l'ọ́mọ ọ̀dọ̀ ni Dino jẹ́

Èso Apple tuntun tí ẹ lè fi pamọ́ fún ọdún kan ti wọ ọjà

Kò sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ mọ lópópóna márosẹ̀ Eko si Ibadan

Àwọn agbébọn pa ènìyàn mẹ́rinlá lásìkò ìjọsìn

  • Ilakaka ijọba apapọ Naijiria ni lati mu idagbasoke ba awọn ti yoo dari eto reluwee jakejado Naijria. Eyi lo mu ki wọn da fasiti yi silẹ
  • Erongba fasiti naa ni ki wọn sọ agbara awọn to n ṣiṣẹ lẹka irinna Naijiria dọtun ki wọn ba le kun oju oṣunwọn
  • Lọwọlọwọ awọn ọmọ Naijiria kan n kẹkọ nipa eto irinna oju reluwe ni China. Wọn n reti pe wọn yoo wa mu idagbasoke ba iwadii nipa ẹka yi.
  • Lọdun 2020 ni ireti wa pe fasiti yi yoo gbera sọ.

Lati igba ti ijọba aarẹ Buhari ti de ori aleefa ni ẹka irinna ti jẹ ọkan lara awọn ẹka ti wọn gbajumọ paapa julọ nipa atunṣe awọn papakọ ofurufu kan lorile-ede Naijiria.

Ijọba Buhari ti ya owo pupọ lati ọdọ orile-ede China lati le ṣe akanṣe iṣẹlẹ lori ileeṣẹ ọkọ oju irin Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Aids Day: Wo bí kòkòrò ààrùn HIV se bẹ̀rẹ̀ lágbàyé!