Ikoyi Prison: Wáyà iná já lu ẹlẹ́wọ̀n márùn ún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n l'Eko, ọ̀pọ̀ w'à níléèwòsàn

Minisita ọrọ abo abẹle Rauf Aregbeṣọ́la naa ti wa nibẹ
Àkọlé àwòrán Wáyà iná já lu ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta lọ́gbà ẹ̀wọ̀n l'Eko, ọ̀pọ̀ w'à níléèwòsàn

O kere tan ẹlẹwọn márùn ún ni o ti di ero ọrun bayii lẹyin ti ina ẹlẹntiriki gbe wọn lọgba ẹwọn Ikoyi ni owurọ ọjọ Aje.

Iroyin ti a gbọ sọ pe ọpọ awọn ẹlẹwọn miran ni wọn wa lẹsẹkan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii nitori iṣẹlẹ naa.

Ohun ti oṣiṣẹ ajọ ẹlẹwọn kan nibẹ ti a fi orukọ bo laṣiri ṣalaye ni pe ina ọba to ṣa dede lagbara lori awọn waya ina kan lọgba ẹwọn naa lo ṣokunfa iṣẹlẹ buruku ọhun.

O fi kun un pe waya ina naa lo ja lori ibusun kan tawọn ẹlẹwọn sun si to fi di pe awọn mẹta jalaisi bo ṣe ṣẹlẹ.

O ni awọn mẹta lo ku loju ẹsẹ ti awọn yooku si ti n gba iwosan nileewosan ọgba ẹwọn naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

O ni ka ni alẹ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni, ko ba buru ju bo ti jẹ naa lọ. O ni ọpọ awọn ẹlẹwọn lo ti dide ti wọn si ti n kọri si ile ẹjọ koowa wọn fun igbẹjọ gbogbo to kan wọn lasiko to fi waye.

Minsita feto ọrọ abo abẹle Rauf Aregbesọla naa ti balẹ si ọgba ẹwọn naa.

Ni kete ti o ba ti bawọn akọroyin wa to wa nibẹ sọrọ la o bun yin gbọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Aids Day: Wo bí kòkòrò ààrùn HIV se bẹ̀rẹ̀ lágbàyé!