Samantha Dalton: Lẹyin ọjọ keji igbeyawo mi, mo padanu kindinrin mi

Barry ati Samantha Dalton Image copyright Samantha Dalton
Àkọlé àwòrán Bàbá mi fún mi kíndìnrín rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí mi

Ki ni ka ti pe eleyi, lẹyin ọjọ meji to ṣe igbeyawo tan, akọroyin BBC, Samantha Dalton lugbadi aarun kindinrin.

Kẹrẹ kẹrẹ, laarin ọdun kan aarun naa le debi wi pe Samantha yoo nilo kindinrin miiran.

Samantha ṣalaye pe baba oun lo doola ẹmi oun lẹyin to fi kindinrin tiẹ silẹ fun un.

''Baba mi lo fun mi lanfaani lẹẹkeji lati wa laye, pẹlu ipinnu nla lati fun mi ni kindinrin kan ninu tirẹ,'' Samantha lo sọ bẹẹ.

Samantha ni bi ere bi ere lẹyin ọjọ meji igbeyawo oun lọrọ naa bẹrẹ nigba t'oun ati ọkọ oun, Justin n lọ ki ẹnikan.

Image copyright Samantha Dalton

Samantha ni dokita oun toni ki oun wa fun awọn ayẹwo kan nibi to ti rii pe ifunpa oun lọ soke nitori awọn kindinrin oun ko ṣiṣẹ daadaa mọ.

Mo gbadun diẹ lẹyin ti wọn fun mi loogun lori ifunpa mi to lọ soke, mo si lanfaani lati rinrin ajo ifẹ lọ si orilẹ-ede Australia pẹlu ọkọ mi bo tilẹ jẹ pe ẹru ṣi n bami pe kindinrin le yọ mi lẹmi nigba kuu gba.

Ṣugbọn ninu oṣu karun un, ọdun 2018, aarun kindinrin yii bẹrẹ si ni wọ mi lara, debi wi pe mo bẹrẹ si ni ru gan an.

Samantha ni bayii loun ṣe dero ile iwosan nibi ti wọn ti sọ pe oun nilo kindinrin mii lati gbadun pada.

Image copyright Samantha Dalton

Baba mi, ọkọ mi ati ẹgbọn mi ṣe ayẹwo lati fun mi ni kindinrin, ṣugbọn baba mi lo ni oun ṣetan lati fun mi ni kindinrin kan ninu tiẹ.

Bayii ni wọn ṣe iṣẹ abẹ fun mi ti mo si wa nile iwosan fun ọsẹ kan, nibi ti mo ti bẹrẹ si ni gbadun diẹdiẹ.

O jẹ ayọ fun mi pe ara baba mi naa ya lẹyin iṣẹ abẹ ti wọn ṣe lati yọ ọkan lara awọn kindinrin fun mi.

Image copyright Samantha Dalton

Barry, baba Samantha ni oun fi kindinrin kan silẹ fun ọmọ oun nitori oun ko fẹ ki iyawo oun, Mandy ati ọmọ oun mii, Laura tabi Justin ọkọ Samantha fi kindinrin kan silẹ ninu tiwọn nitori wọn si kere lọjọ ori si oun.

Barry ni ko yẹ ki ọkan lara awọn ọmọ oun, iyawo oun tabi ọkọ ọmọ oun maa gbe ile aye pẹlu kindinrin kan nitori wọn ko tii dagba to oun nitori oun ti sun mọ ọgọta ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele