Opay bikes impoundment: Opeifa ní gbogbo ọlọ́kadà lòfin dè láti rìn ní mọ́rosẹ̀ Eko

Awọn ọkada Opay Image copyright Twitter/Mr Festus Emeka
Àkọlé àwòrán Opeifa ní gbogbo ọlọ́kadà lòfin dè láti rìn ní mọ́rosẹ̀ Eko

Irọ ni pe LASTMET lo ko ọkada Opay kuro nilẹ- Ọpẹifa

Ọgbẹni Kayode Opeifa, tó jẹ alaga ajọ to mojuto igbokegbodo ọkọ ati imuṣẹ ofin to de igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko (Lagos State Traffic Monitoring and Enforcement team) sọ pe ajọ naa kọ lo ko awọn 'ọkada' to jẹ ti ile iṣẹ Opay lọjọ Aje.

Ọgbẹni Opeifa sọ pe ajọ LASTMET kii mu ọlọkada, o ni awọn n ba awọn ajọ to n mu eeyan to ba ru ofin ṣiṣẹ pọ ni.

Ṣugbọn Opeifa ṣalaye pe ajọ yoo wu to ba jẹ pe oun lo ko awọn ọkada lagbara labẹ ofin lati gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Opeifa fikun ọrọ rẹ pe ti ile iṣẹ Opay ba forukọ silẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko, iyẹn ko fun wọn lagbara lati tapa s'ofin ipinlẹ Eko lori gigun alupupu l'Eko.

O ṣalaye siwaju si pe ofin ipinlẹ Eko lodi si ki ọkada maa gba ọna mọrosẹ nipinlẹ Eko.

Alaga ajọ LASTMET ni ko si iyatọ laarin ọkada Opay atawọn ọkada yoku ti wọn ba gba ọna mọrọsẹ niluu Eko.

Image copyright Twitter/Otunbabakush1
Àkọlé àwòrán Opeifa ní gbogbo ọlọ́kadà àti Opay lòfin dè láti gba ọ̀nà mọ́rosẹ̀ l'Eko

O ni kii ṣe pe ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ ati imuṣẹ ofin to de igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko dojule Opay nikan.

Opeifa tun ni ofin ipinlẹ Eko ko faaye gba fifi ọkada ṣiṣẹ kero lori opopona marosẹ nipinlẹ Eko.

Kini èrò akọṣẹmọṣẹ lori eto ọrọ aje nipa igbeṣe ijọba Eko lori kiko ọkada nilẹ?

Ẹwẹ, onimọ nipa ọrọ-aje, Bisi Iyaniwura to ba BBC Yoruba sọrọ fidi rẹ mulẹpe o yẹ ki ijọba ipinlẹ Eko yẹ ara rẹ wo lori mumu awọn ọlọkada Opay lẹyin ti wọn ti forukọ silẹ pẹlu ijọba.

Ọgbẹni Iyaniwura sọ pe ijọba ni lati ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu ọlọkada Opay atawọn ọlọkada mii niwọn igba ti wọn ko ba tapa s'ofin to de igbokegbodo ọkọ niluu Eko.

Bakan naa ni Iyaniwura sọ pe igbesẹ ijọba yii le da rogbodiyan silẹ nitori o le sọ ọpọlọpọ ọdọ di alainiṣẹ ni eyi to dẹ le tun fa iwa ipa ati ole jija lawujọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Bakan naa lo mẹnuba aiṣiṣẹ bo ti yẹ awọn oṣiṣẹ ijọba to n risi ọrọ lilọ bibọ ọkọ ni eyi to n ṣafikun si iṣorọ sunkẹrẹ-fakẹrẹ loju popo ni eyi ti ọpọ fi n gun ọkada dipo mọto nigba ti oju ba ti n kan wọn..

Akitiyan BBC Yoruba lati gbọ lati ẹnu awọn alaṣẹ ile iṣẹ Opay, ja si pabo titi di asiko ti a fi kọ iroyin yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA