Saraki: Ilé ẹjọ́ ní yóò yanjú ọ̀rọ̀ lórí ilé mí tí Ìjọba gbẹ̀sẹ̀ lé

Aworan oṣiṣẹ EFCC niwaju ile Saraki ti wọn gbẹsẹ le nilu Ilorin Image copyright EFCC
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ ní yóò yanjú ọ̀rọ̀ lórí ilé mí tí Ìjọba gbẹ̀sẹ̀ lé

Aarẹ ana ni ile aṣofin agba orile-ede Naijiria Sẹnẹtọ Bukola Saraki ti fesi pe ile ẹjọ ni yoo yanju ọrọ laarin oun ati ijọba Naijiria to gbẹsẹ le ile rẹ kan to wa nilu Ilorin.

Lọjọ Aje tii ṣe ọjọ keji, oṣu Kejila ni ẹka ajọ EFCC to wa nilu Ilorin gba idajọ lọdọ adajọ Ridwan Aikawa pe ki Saraki jọwọ ile naa fun ijọba tori pe ọna aitọ lo gba kọ ọ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Saraki fi sita fawọn oniroyin, o ni igbesẹ EFCC tapa si ofin nitori ile ẹjọ giga lAbuja to ti paṣẹ pe ki wọn ma ṣe gbe igbesẹ lori gbigba ogun Saraki kankan.

Yusuf Olaniyọnu to jẹ agbẹnusọ fun Saraki ṣalaye ninu rẹ pe: ''Irọ pọnbele ni ọrọ ti EFCC sọ pe ọna aitọ ni Saraki fi kọ ile naa.''

''Ohun to ṣẹlẹ ni pe ijọba Kwara da ninu owo ti wọn fi kọ ile naa ni ibamu pẹlu ofin to de sisan owo ifẹyinti fawọn Gomina ati igbakeji wọn ti Saraki si fi owo ara rẹ pari eleyi to ku''

Olaniyonu sọ pe iṣẹ ko bẹrẹ lori ile yi titi di asiko ti Saraki fẹ pari saa rẹ gẹgẹ bi Gomina ti o si fi iwe sọwedowo san owo kikọ ile naa

O wa tẹnumọ pe Saraki yoo tako igbesẹ yi ni ile ẹjọ lati le fi igbagbọ rẹ ninu titẹle ofin ilẹ yi rinlẹ .

Yatọ si ile Ilorin, ajọ EFCC ti n tọ pinpin awọn dukia Saraki ti Iroyin si kan nigba kan pe wọn gbẹsẹ le ile rẹ kan ni adugbo Ikoyi nilu Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

Faakinfa laarin Saraki ati Ijọba Naijiria ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Nigba to wa lori oye gẹgẹ bi Aarẹ ile aṣofin Naijiria,ajọ to n risi igbogun ti awọn to n lu owo ilu ni ponpo ati gbigbogun ti iwa ibajẹ ICPC naa pe lẹjọ.

Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Àsòfin. Bukola Saraki ti sọ fún Àjọ EFCC pé kí wọ́n fi òun sílẹ̀, kí wọ́n yé é dìtẹ̀ mọ́ òun.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Aids Day: Wo bí kòkòrò ààrùn HIV se bẹ̀rẹ̀ lágbàyé!