NUC: Àjọ tó n rí si ọ̀rọ̀ fásitì kéde ayédèrú kòfésọ̀ tó tó ọgọ́rùn ún

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati foju awọn ayederu olukọ fasiti han sita

A ti ri to ọgọrun unawọn ọjọgbọn ti wọn kii ṣe ootọ ni fasiti NAijiria kakiri- Abubakar

Ajọ to n mojuto ọrọ ile iwe giga ni Naijiria, NUC ti kede pe oun ti ṣawari awọn ayederu ọjọgbọn kaakiri fasiti Naijiria.

Ojọgbọn Abubakar Rasheed to jẹ akọwe agba ajọ naa lo fi ikede yii sita ninu atẹjade ajọ naa to jade fun iṣẹlẹ oṣu kọkanla.

Wọn ni awọn ti forukọ awọn ayederu kofẹsọ wọnyii ranṣẹ si awọn fasiti ti wọn ti n ṣiṣẹ fun igbesẹ to yẹ.

Rasheed ni idi ti awọn ko ṣe kọkọ fi awọn orukọ yii sita ni pe ki ajọ NUC fun fasiti kọọkan laaye lati lọ fidi iwadii NUC mulẹ ki wọn ri otitọ ọrọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSex Education: Ẹkọ ibálopọ̀ ko tó l'awọ́n ọ̀dọ́ ṣe n wá a lorí ayélujára

Rasheed sọ pataki ki awọn adari fasiti kọọkan lọ ṣe iwadii to yẹ lori awọn olukọ ti ọrọ kan ni kiakia lasiko ti ajọ NUC n ṣeto apero fawọn adari fasiti ni Naijiria.

O ni to ba ti di gbendeke ipari oṣu kejila ti wọn fun awọn adari fasiti lati gbe igbese to yẹ ajo NUC yoo gbe awón orukọ awọn olukọ ti igba ọrọ yii ṣi mọ lori sita faraye lati ri.

Abubakar Adamu Rasheed ṣalaye pe aṣiri ko deede tu bikoṣe igbesẹ ajọ NUC ti wọn ni ki gbogbo awọn kofẹsọ Naijiria fi awọn iwe ẹri wọn ṣọwọ soju opo ajọ NUC fun ayẹwo.

O ni lasiko yii ni NUC n ṣawari awọn ayederu iwe ẹri ti ko si fasiti to sọ wọn di ọjọgbọn.

Koda, Akọwe agba ajọ NUC yii tun kilọ fawọn adari fasiti ki wọn ṣe ohun ti o tọ lori awọn akẹkọọ to n jade ni fasiti koowa wọn

O ni NUC ti gba iwe ẹsun lọdọ adari ajọ awọn agunbanirọ pe awọn iwe ẹri awọn agunbanirọ fasiti miran mu ifura dani ti wọn ba n bọ wa sin ilẹ babawọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Bakan naa lo kilọ fawọn adari fasiti lati lọ mojuto iṣe ati ọna ikẹkọọ awọn ile iwe giga ti wọn jọ n ṣe ajọṣepọ ikẹkọọ fawọn akẹkọọ, yala ile ikọṣẹ olukọ NCE tabi awọn ile iwe gbogboniṣe tabi awọn eto agbelekawegboye Sandwish.

Bakan naa ni Rasheed ni ko si aaye fun olukọ fasiti kan lati maa ṣiṣẹ olukọ kọja ile iwe giga meji o pọju.

Ati pe wọn gbọdọ maa ṣiṣẹ wakati mẹjọ wọn pe o keere ju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA