Akitoshi Okamoto: Òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì, wọ gbaga ọlọ́pàá torí pé o pé ní 24,000

Aworan apoti ẹrọ ibanisọrọ kan
Àkọlé àwòrán Òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì, wọ gbaga ọlọ́pàá torí pé o pé ní 24,000 laarin ọjọ mẹjọ

Ọwọ awọn ọlọpaa lorilẹ-ede Japan ti tẹ oṣiṣẹfẹyinti ọmọ ọdun mọkanlelaadọrin kan lagbegbe Saitama.

Wọn ni o n lo oniruuru nọmba ibanisọrọ lati fi daamu ileeṣẹ ibanisọrọ kan lorilẹ-ede naa.

Oṣiṣẹfẹyinti ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Akitoshi Okamoto ni wọn ni o pe ileeṣẹ ibanisọrọ naa ni igba ẹgbẹrun mẹrinlelogun, 24,000 laarin ọjọ meje lati beere ọpọlọpọ ibeere ati ẹsun pe wọn tẹ oju ofin adehun oun pẹlu wọn mọlẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ibanisọrọ naa, (KDDI) sọ, Alagba Okamoto n binu gan an ni pe awọn ariwo ibanisọrọ redio n farahan lori oju opo ibanisọrọ oun, eleyi to mu ko maa pe wọn ni tẹle-n-tẹle lati fi ẹhonu rẹ han.

Lakọkọ, KDDI ko fẹ gbe igbesẹ ofin lori rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn onibara wọn ṣugbọn nigba ti ipe rẹ di lemọlemọ ti wọn ko si ri imu mi mọ tabi raye gbọ tawọn onibara yoku mọ ni wọn fi gbe ọlọpaa dide.

Awọn ileeṣẹ iroyin kan tilẹ sọ pe o ṣeeṣe ki ipe alagba naa gan an ju ẹgbẹrun mẹrinlelogun lọ.

Wọn ni ọkẹ aimoye ipe miran ni alagba Okamoto tun pe lawọn ibanisọrọ igboro ti wọn tilẹ ni o tun n sọ oriṣiriṣi ọrọ kobakungbe sawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Awọn kan tilẹ sọ pe o ni ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ibanisọrọ naa o fi ẹsẹ wọn rin wa ba oun nile lati tọrọ aforiji fun titẹ adehun aarin oun ati wọn loju mọlẹ.

Ni kete to ba si ti rii pe oju opo rẹ ba ti wọle ni yoo pa foonu rẹ.

Ẹsun fifi iwa jibiti di iṣẹ ẹlomiran lọwọ lawọn ọlọpaa fi gbe; ofin yii si faaye ijiya ofin silẹ fun ẹnikẹni to ba di awọn ileeṣẹ lọwọ lati ma ṣe ojuṣe wọn.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, alagba Okamoto ṣalaye fun ọlọpaa pe oun kan ni ẹni ti wọn fi iya jẹ lori ọrọ naa.