Ikoyi prisons: Lọjọ Aje ni waya ina ja lu awọn ẹlẹwọn kan ti o si ran wọn lọ sọrun

Abawọle ọgba ẹwọn Ikoyi
Àkọlé àwòrán Lọjọ Aje ni waya ina ja lu awọn ẹlẹwọn kan ti o si ran wọn lọ sọrun.

Ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria ti ni awọn ko tii kede orukọ awọn ẹlẹwọn to kagbako iku ojiji

Awọn alaṣẹ Ọgba ẹwọn nipinlẹ Eko lo fi ọrọ yii to BBC News Yoruba leti nilu Eko.

Ni ọjọ Aje ni iroyin lu sita nipa iku awọn ẹlẹwọn marun un kan lọgba ẹwọn to wa ni Ikoyi nilu Eko lẹyin ti waya ina ja lu wọn lori ibusun eleyi to ran awọn meje miran lọ si ileewosan.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọgba ẹwọn naa ni ohun ti awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria n ṣe lori ọrọ naa bayii ni lati kọkọ fi ọrọ naa to awọn mọlẹbi awọn to ku naa lọwọ.

Minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Arẹgbẹṣọla to wa lara awọn oṣiṣẹ ijọba to kọkọ de ọgba ẹwọn naa lọjọ Aje pẹlu ko ṣai fi da awọn eeyan loju pe gbogbo eto to yẹ nijọba a ṣe.

O ni igbesẹ lati ri i pe wọn tan ina wa idi ohun to fa iṣẹlẹ buruku naa ni wọn yoo ṣe.

Bakan naa lo ni wọn yoo gbe igbimọ iwadii kan kalẹ lati rii pe ilana ofin gbogbo to yẹ waye lori iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Ninu ọrọ tirẹ, Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria, Ja'afaru Ahmed ni ara ohun to n ba ileeṣẹ ọgba ẹwọn finra naa ni apọju awọn ẹlẹwọn lọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFUTA: Àwọn mẹ́jọ ló ṣíná ìyà fún Bolu ní FUTA

Fun apẹrẹ, o ni ẹgbẹrin ẹlẹwọn ni wọn kọ ọgba ẹwọn naa fun lọdun 1955 ti wọn kọ ọ, ṣugbọn lọwọ yii o le ni ẹgbẹrun mẹta awọn eeyan to wa ninu rẹ.

Ati pe ninu ẹgbẹrun mẹta o le naa, o le ni ẹgbẹrun meji nibẹ to jẹ pe wọn n reti idajọ ni.

Pẹlu bi ọrs ti ri yii, ko tii si ẹni lee sọ boya awọn ẹlẹwọn to ti gba idajọ lawọn marun to ku naa abi awọn to n reti igbejọ ati idajs ile ẹjọ wa lara wọn.