Buhari ṣè ìfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ ìjagun ológun tiwantiwa ní Kaduna

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright Twitter/@BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Buhari ṣèfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ ìjagun ológun tiwantiwa ní Kaduna

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ifilọlẹ ọkọ ijagun tiwantiwa lati le sọ agbara awn ọmọ ogun Naijiria di ọtun,

Ni ilu Kaduna lariwa orile-ede nibi ayẹyẹ apero ọlọdọọdun ọga ileeṣẹ ologun Naijiria ni ifilọlẹ yi ti waye lọjọ iṣẹgun.

Ọkọ naa ti o le tẹ ado oloro mọlẹ loju ogun ni wọn pe orukọ rẹ ni Ezugwu MRAP.

Aarẹ Buhari kan saara si awọn ọmọ ogun Naijiria fakitiyan wọn nipa kikoju awọn agbesunmọmi ati didaabo bo orile-ede Naijiria

Image copyright Twitter/@BashirAhmad

Aarẹ ṣeleri atilẹyin ijọba rẹ fun ileeṣẹ ologun ki wọn baa le ri awọn erongba wọn muṣẹ.

O tun ni alaafia mọlẹbi wọn ṣe pataki si ijọba.

Aarẹ ni: ''Mo ṣakiyesi ajọṣepọ laarin ẹka imọ ẹrọ ileeṣẹ to ṣe ọkọ yi pẹlu awọn ileeṣẹ tiwantiwa lati gbe iṣẹ ọwọ larugẹ ati idagbasoke ileeṣẹ ologun wa''

O tun sọ pe inu oun dun pe ''akitiyan tawọn ologun Naijiria n ṣe ti bẹrẹ si ni yọri si rere pẹlu ọkọ ti wọn ṣe yi''

Ẹwẹ aarẹ Buhari tun kan saara sawọn ọmọ ogun Naijiria fun ifarajin wọn forile-ede Naijiria.