Ọwọ́ palaba kánsẹ́lọ̀ tẹlé rí olórí adigunjalè tó n jí ọkọ̀ ní Kwara segi

Aworan Kansẹlọ tẹlẹ ri ti EFFC sọ pe oun ni baba isalẹ awọn adigunjale to n ji ọkọ Image copyright EFCC

Kansẹlọ tẹlẹri kan ni ijọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara ti ko si panpẹ ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria, ìyẹn EFCC.

Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o jẹ olori awọn adigunjale to n fi ọna ẹburu ji ọkọ ayọkẹlẹ.

Loju opo ajọ naa ni wọn fi ikede yi si pẹlu alaye pe ọgbẹni Samuel Opeyemi Adeojo ni o jẹ agbatẹru awọn adigunjale kan ti wọn maa n fi ọna ẹburu ji ọkọ awọn onisowo ọkọ.

Gẹgẹ bi ohun ti ajọ naa sọ, wọn ni o to ọjọ mẹta ti awọn ti n wa Adeojo ki o to wa di pe ọwọ tẹ ẹ.

O kere tan wọn ti fi idi ẹjọ mẹta mulẹ lori ẹsun ti wọn fi kan ikọ adigunjale yii ti wọn si ti gba ninu awọn ọkọ ti wọn ji gbe lọwọ wọn.

Awọn ọkọ naa wa ni ileeṣẹ ajọ EFCC to wa ni ilu Ibadan.

Iwadii EFCC gẹgẹ bi alaye wọn ṣe, ni o jẹ ki wọn mọ ọgbọn tawọn ole naa n lo lati fi ji ọkọ awọn eeyan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele