Fake Pastors: Bunmi àti Rukayat ni agbódegbà àwọn afurasi pasitọ náà

Favour &Favour Image copyright others
Àkọlé àwòrán Rukayat Folawewo ni òun ri iṣẹ́ ìyànu gba lọ́dọ̀ pasitọ Favour David lẹ́yìn ìjàmba ọkọ tó lágbara

Awọn òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ́múyẹ́ to n rí si ìwádìí ọ̀dáran nípinlẹ̀ Eko ti mú àwọn mẹ́rin kan tọ fi mọ olùsọ́aguntan méji.

Wọn fẹ̀sun kan pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ amí ati iṣẹ ìyanu èké ti wọ́n si n purọ gbówó lọ́wọ́ àwọn olùgbé Lekki àti Epe nípínlẹ̀ Eko.

Àwọn pásìtọ tí wọ́n fẹ́sùn kan ní Favour David ati Favour Chimobi pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Rukayat Folawewo àti Bunmi Joshua, láti maa ṣe ìṣẹ́ jìbìtì wọ́n.

Agbẹ́nusọ ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Eko Bala Elikana, sọ nínú àtẹjáde kan pe àwọn afurasí náà maa n wá ọmọ ìjọ fún ìjọ Wonders Assembly Ministry to waà ni àdojúkọ Lagos Business School ní márosẹ̀ Lekki/Epe ni Ajah.

Elkana ni "a mú afurasí mẹ́rin ti wọ́n maa n fi iṣẹ́ ìyanu òfége lo gbájuẹ̀ fún àwọn ara ilú ti ko fúra, wọ́n ṣe asọtẹlẹ, awọ́n miran a jẹri èké, èyi ni wọn n lò láti gbowó lọ́wọ wọ́n ti wọ́n a sì tún maa lo àwọn ọna miran láti kó ọrọ̀ jo."

Elkana ni lẹ́yin ti ará ìlú tàwọn lolobó ni àwọn gbé ìgbésẹ̀ ti àwọn si mú àwọn obinrin méji, Rukayat Folawewo àti Bunmi Joshua ti wọ́n n ṣe bi ọmọ ìjọ naa ti wọ́n sì ri iṣẹ́ ìyànú ìwòsàn gbà láti ọwọ pásìtọ lẹ́yìn ìjàmba ọkọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

"Ní ti Bunmi Joshua nítirẹ, oun jẹ́ri èké fún àwọn ọmọ ìjọ naa pé ọmọ oun to ti kò gbọ́ran ti ko si lè sọrọ ri ìwòsàn gbà.

O tun ni o sì ti n gbọ́ran àti sọ̀rọ̀ báyìí lábẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ pásìtọ Favour Chimobi ti ìjọ Elijah Ministry ní Port Harcourt ti oun ati pasitọ David Favour jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.

Elkana sàlàyé pé ìwádìí fihan pé ìrọ panbele ni gbogbo ẹ̀rí náà, ti wọ́n si mu àwọn afurasi náà lásìkò ìṣọ́ oru.