Mobolaji Johnson: Yàtọ̀ sí Onikan stadium, wo àwọn dúkìá ìlú tí a fi sọ orí àwọn akọni

Papa ofurufu MMIA Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Yàtọ̀ sí Onikan stadium, wo àwọn dúkìá ìlú tí a fi sọ orí àwọn akọni

Gẹgẹ bii ara eto ati ṣe iranti iṣẹ ribiribi ati ipa manigbagbe ti oloogbe Mobọlaji Johnson ko nigba aye rẹ, gomina ipinlẹ Eko Sanwo-Olu ti fi orukọ rẹ sọ papa iṣire Onikan nilu Eko.

Eyi kii ṣe akọkọ igbesẹ bayii. Ọpọ igba lawọn ijọba lẹka gbogbo ti maa n fi awọn ohun amayedẹrun ilu sọ orukọ awọn akọni ati akinkanju ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan.

Image copyright others

Eyi ni diẹ lara awọn awọn dukia ilu ti wọn ti fi sọ ori awọn eekan kan lawujọ.

Papakọ ofurufu Murtala Muhammed (Murital Muhammed International Airport) Ilu Eko

Papakọ ofurufu ilu Eko jẹ ọkan lara awọn papakọ ofurufu ti igbokegbodo baluu ti n waye julọ ni ilẹ Afirika.

Ni asiko ogun agbaye keji ni wọn kọ papakọ ofurufu yii.

Papakọ ofurufu ilu Eko ni orukọ rẹ tẹlẹ ki wọn to yi orukọ rẹ pada si papakọ ofurufu Murtala Muhammed.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability: Kò sí ẹni tí àkàndá kò lè ya ilé rẹ̀- Ayọdele

Wọn ṣe eyi ni iranti olori ijọba ologun lorilẹ-ede Naijiria nigbakan ri, Ọgagun agba Murtala Muhammed to ku ni ọdun 1976.

Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, (Obafemi Awolowo University) OAU, Ile Ifẹ

Image copyright oau

Orukọ fasiti yii nigba ti wọn daa silẹ ni fasiti Ile Ifẹ, iyẹn University of Ife, nigba ti ijọba ẹkun iwọ oorun Naijiria nigba naa ni ọdun 1961 daa silẹ.

Wọn wa yi orukọ rẹ pada si fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ ni ọdun 1987 lẹyin iku Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ.

Awolowo ni ọpọ gba pe oun ni baba iṣelu ni eyi ti wọn ṣi n ri aritọkasi iṣẹ to ṣe bii NTA, Liberty Stadium ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Moshood Abiola stadium, (National Stadium) Abuja

Image copyright Getty Images

Papa iṣire apapọ orilẹ-ede Naijiria, iyẹn National Stadium ni orukọ papa iṣere yii tẹlẹ ki wọn to yi orukọ rẹ pada si papa iṣere Moshood Abiọla ni ọdun 2019.

Papa iṣere naa to wa lara awọn papa iṣere aadọta ti owo ti wọn fi kọ wọn wọn julọ lagbaye ni wọn fi sọri Abiọla ẹni ti ọpọ n pe ni akin eto iṣejọba tiwantiwa ni Naijiria.

Abiola naa dije dupo aarẹ Naijiria ninu idibo ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993 ni eyi ti ọpọ gba pe o wọle.

Papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, (Nnamdi azikiwe airport ) Abuja

Image copyright others

Papakọ ofurufu Abuja ni orukọ papakọ ofurufu yii ni igba ti wọn kọ ọ ni ọdun 2000.

Orukọ Ọmọwe Nnamdi Azikwe to jẹ aarẹ alagbada akọkọ lorilẹ-ede Naijiria ni wọn fi sọ papakọ ofurufu naa eyi to wa ni olu ilu orilẹ-ede Naijiria.

Fasiti Usman Dan Fodio, (Usmanu dan Fodio university) Sokoto

Image copyright usman dan fodio university

Ni ọdun 1975 ni wọn da fasiti yii silẹ gẹgẹ bii fasiti ilu Sokoto.

Ọkan lara awọn fasiti mejila ti ijọba apapọ da silẹ lọdun naa ni. Wọn fi sọ orukọ Usman dan Fodio to jẹ oludasilẹ agbegbe Sokoto.

Papa iṣere Mobọlaji Johnson (Mobolaji Johnson Stadium) Ilu Eko

Image copyright others

Papa iṣere ti wọn kọkọ kọ sibẹ wa saye ni ọdun 1930 nitosi gbagede Tafawa balewa Square.

Lọdun 1936 ni wọn fi sọ orukọ Ọba ilẹ Gẹẹsi nigba kan ri, King George V. Lọdun 1963 si 1973 ni orukọ rẹ yipada di papa iṣere ilu Eko, Lagos City Stadium.

Ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 2019 ni gomina ipinlẹ Eko, Sanwo Olu Babajide, kede iyipada orukọ rẹ si papa iṣire Mobọlaji Johnson.

Eyi jẹ ni iranti Ọgagun Mobọlaji Johnson to fi igbakan ri jẹ gomina ologun ni ipinlẹ Eko laarin ọdun 1966 si 1967.