Insecurity: Monguno ní àsìkò ti tó láti f'òpin sí Almajiri ní Nàìjíríà

Awọn Almajiri Image copyright Getty Images

Oludamọran fun ijọba lori ọrọ aabo, Babagana Monguno ti kepe ijọba lati fopin si eto ẹkọ Almajiri to wọpọ lapa ariwa orilẹede Naijiria.

Nigba to n sọrọ nibi apero kan to da lori ọna lati ṣeto aabo to mọyan lori, Monguno ṣalaye pe lai fopin si Almajiri bayii, yoo pada wa ṣakoba fun orilẹede Naijiria lọjọ iwaju.

Loṣu kẹfa to kọja ni Monguno sọ pe ijọba apapọ n gbero lati fi opin si Almajiri ki iru awọn ọmọ le lanfaani lati lọ si ile iwe.

Ọgbẹni Monguno fifi opin si Almajiri kan gbogbo eeyan kii ṣe ijọba nikan lọrọ naa kan.

Bakan naa lo sọ nibi apero ọhun pe ọrọ eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria nii ṣe pẹlu awọn ọta ile ti wọn ṣi ilẹkun fun ti ita.

O ṣalaye siwaju si pe awọn kọlọnbiti ẹda kan ni wọn lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan nilẹ okere lati maa da eto alaafia ru ni Naijiria.

Monguno ni ijọba fẹ lo apero lori eto aabo lati wa ojutuu si iṣoro eto aabo to mẹhẹ, eto ẹkọ ti ko munadoko ati awọn idojukọ pẹlu eto ilera ni Naijiria.