Sowore: Atiku Abubakar, Oby Ezekwesili, àtawọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ órí ohun tójú Sowore rí ní kóòtù

Sowore atawọn agbejọro rẹ ni ile ẹjọ

Lọjọ Ẹti ni gbẹgẹdẹ gbina ni gbegede ile ẹjọ giga apapọ kan ni ilu Abuja ti ṣe olu ilu Naijiria nigba ti awọn agbofinro ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ya wọ ile ẹjọ lati fi tipatipa mu Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ajafẹtọ ọmọniyan pada si ahamọ wọn.

Ni alẹ Ọjọbọ, ọjọ karun un oṣu kejila ọdun 2019 ni ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS tu Soworẹ silẹ lahams wọn lẹyin aṣẹ ile ẹjọ to ni ki wọn ṣe bẹẹ laarin wakati mẹrinlelogun ki wọn si tun san owo gba mabinu ẹlẹgbẹrun lọna ọgọrun naira fun un.

Ki wọn to de ile ẹjọ lowurọ ọjọ Ẹti ni iroyin ti jade pe DSS yoo gbe Soworẹ, ṣugbọn awọn amofin rẹ ni awọn ti mọ si awọn si ti gbe igbesẹ lori rẹ.

Nibayii, awọn eekan ilu nilẹyii ati loke okun ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ yii.

Aṣiwaju ajafẹts araalu lagbaye, Ọjọgbọn Oby Ezekwesili wa lara awọn to kọkọ gbohun soke tako igbesẹ naa. O ni ko si bi aarẹ Buhari ṣe lee sọ pe oun ko mọnipa eewọ ti awọn ileeṣẹ agbofinro DSS n jẹ lori ewe iṣejọba tiwantiwa Naijiria.

Oby Ezekwesili ni aarẹ ni oludari agba fun ileeṣẹ DSS, afi ko tete yara paṣẹ fun Ọga agba ajọ naa lati tẹle ofin ile ẹjọ ki wọn si tu Soworẹ silẹ

Ẹwẹ, ninu ọrọ tirẹ, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ ninu eto idibo to kọja, Alhaji Abubakar Atiku sọ ọ yanya pe ibanujẹ nla lo jẹ fun oun ohun to ṣẹlẹ ni ile ẹjọ loni nipa ṣoworẹ.

Image copyright Twitter/Sahara Reporters

"Ko si igba kan ninu itan oṣelu Naijiria ti irufẹ ohun to ṣẹlẹ si adajọ kan loni tii ṣẹlẹ."

Atiku ni gbogbo awọn alagbara orilẹede Naijiria lo gbọdọ mọ pe iṣejọba tiwantiwa lo wa lode ni Naijiria kii ṣe ti afagidijaye.

O wa rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lati dide ja fun idaabobo eto iṣejọ awarawa rẹ.

Oniruuru ọrọ si lawọn ọmọ Naijiria n sọ lori ayelujara. Bi awọn kan ṣe n pariwo pe ki ijọba bọwọ fun ofin lawọn miran n ke gbare pe, ijọba atawọn ileeṣẹ agbofinro n tigi boju ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria.

DSS fi ipá mú Ṣowore padà s'átìmọ́lé l'Abuja

Pẹlu tipa ti ikuuku ni awọn oṣiṣẹ ajọ DSS fi fẹ mu Omoyele Ṣowore pada si atimọle wọn lọjọ Ẹti.

Eleyi ṣẹlẹ ninu ile ẹjọ niluu Abuja nibi ti awọn akoroyin ti faake kọri pe awọn ko nii gba ki wọn u Ṣowore pada si gbaga.

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ ajọ DSS tun gbiyanju lati yinbọ fun.

Adajọ Ijeoma Ojukwu ti sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kọkanla oṣu keji ọdun 2020 lẹyin ti awọn agbẹjọro Ṣowore ati ajọ DSS beere pe ki ijọba sun igbẹjọ naa siwaju.

Agbẹjọro fun Ṣowore, Femi Falana ṣalaye pe ajọ DSS fi ipa mu Ṣowore nitori pe wọn fẹ fi ẹsun miiran kan an.

Kò lè ṣeéṣe kí DSS tún dá Ṣowore padà sí àtìmọ́lé wọn

Agbẹjọrọ fun Omoyele Ṣowore ati Adebayo Bakare, Femi Falana sọ pe ẹni eegun n le ko maa rọ ju lọrọ awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, nitori bi o ti n rẹ araaye lo n rẹ ara ọrun.

Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ti ajọ tu Ṣowore ati Bakare silẹ tan l'Ọjọbọ, Falana wi pe ko ṣeeṣe ki ajọ DSS tun mu awọn mejeeji pada lọnii ọjọ Ẹti.

Ṣowore ati Bakare gba ominira lẹyin ti ile ẹjọ giga l'Abuja paṣẹ pe ki ajọ DSS fi wọn silẹ laarin wakati mẹrinlelogun, lẹyin naa lawọn n sọ pe o ṣeeṣe ki DSS tun dawọn pada si gbaga lonii ọjọ Ẹti.

Image copyright Sahara reporters

Amọ, Falana ni ko si ohun to jọ bẹẹ, o ni digbi lawọn n duro de ajọ DSS lori igbesẹ mii ti wọn ba fẹ gbe lori ọrọ Ṣowore.

Falana tun fidi rẹ mulẹ pe adajọ ni ki ajọ DSS san ẹgbẹrun un lọna ọgọrun un naira lori bi wọn ṣe kọ lati paṣẹ ile ẹjọ mọ pe ki wọn fun Ṣoworẹ lominira

Itusilẹ Omoyele Ṣowore waye lẹyin ti o ti lo ọjọ marundilaadoje ni ahamọ awọn DSS.

Oniruuru idajọ lo ti waye eyi ti awọn ile ẹjọ lorilẹede Naijiria ti ni ki wọn fi silẹ ṣugbọn ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ DSS kọ jalẹ pẹlu oniruuru awawi.

Amọṣa ni ọjọbọ ni ileẹjọ miran tun pa aṣẹ ki ileeṣẹ Ọtẹlẹmuyẹ DSS o tu u silẹ laarin wakati mẹrinlelogun.

Image copyright Instagram/Omoyele Sowore

Ireti wa pe yoo tun farahan ni ile ẹjọ ni ọjọ Ẹti ni itẹsiwaju igbẹjọ rẹ.

Ni ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni awọn agbofinro DSS lọ gbe Ọmọyẹle Soworẹ lori ẹsun pe o n ṣe agbatẹru awọn iwọde #revolutionnow eleyi to n beere fun iṣejọba rere lorilẹede Naijiria.

Ni ajọ kẹfa oṣu kọkanla ni ọgbẹni Soworẹ kọkọ mu ileri beeli akọkọ ti ile ẹjọ fun ṣẹ ṣugbọn ti ileeṣẹ DSS ko tuu silẹ.

Image copyright Facebook/Omoyele Sowore

Ọru ifisahamọ Sowore ti mu ọpọlọpọ awọn ajọ ilẹ okeere ati ti Naijiria pẹlu lati kigbe si ijọba apaọ lati bọwọ fun ofin ṣugbọn ti ileeṣẹ DSS kuna lati tu u silẹ gẹgẹ bi awọn aṣẹ iṣaaju lati ile ẹjọ.

Bakan naa ni ileeṣẹ DSS tun da Olawale Bakare naa silẹ.

Awọn mejeeji yi ni ijọba apapọ n fi ẹsun iditẹ gbajọba kan.