Sola Allyson, olorin Ẹmi ni orin àìmọ ààlà ìfẹ́ àti àṣejù ń mú àwọn olólùfẹ́ kóbá àye àwọn olórin

Lati Eji Owurọ, Ọpẹ,Ire, Imoore, Imisi titi de ori Ìrì ti o ṣẹṣẹ gbe jade, Ṣọla Allyson aya Ọbaniyi kii ṣe olorin ti a lee fi ọwọ rọ sẹyin ninu agbo orin ẹmi, imisi tabi idanilaraya lorilẹede Naijiria ati lagbaye.

Awo orin rẹ tuntun to ko jade fun un ni anfani lati BBC News Yoruba sọrọ lori ohun to n fun un ni Imisi lati gbe awọn orin agbọgbarimu jade ni gbogbo igba.

Awọn koko bii iyatọ laarin orin rẹ atawọn ẹya orin yoku, ajọṣepọ rẹ pẹlawọn ololufẹ orin rẹ titi kan bi o ṣe n ṣe amojuto iṣẹ orin rẹ ati ẹbi ni o sọrọ nipa rẹ.

Bakan naa lo mẹnuba awọn nnkan miran laisi pe ọkan tako ọkan ninu rẹ kun ara ohun to ba BBC News Yoruba sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii.

Ẹ wo o ni agbogbadun!