Open Treasury Portal: APC ní ètò tó ń ṣàmójútó ìnáwó ẹ̀ka ìjọba yóò gbógunti ìwà àjẹbánu

owo naira Image copyright @others
Àkọlé àwòrán APC ní ètò tó ń ṣàmójútó ìnáwó ẹ̀ka ìjọba yóò gbógunti ìwà àjẹbánu

Ijọba apapọ ti ṣe ifilọlẹ apo eto iṣuna (Open Treasury Portal) eleyi ti yoo fun ijọba lanfaani lati maa ṣalaye bi ijọba ṣe n na wo to wọle sapọ ijọba.

Akọwe agba ajọ to n ṣafihan didari awọn ile isẹ (Nigeria Extractive Industries Transparency Initiative, NEITI), Waziri Adio lo fọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.

Image copyright Twitter/Presidency
Àkọlé àwòrán APC ní ètò tó ń ṣàmójútó ìnáwó ẹ̀ka ìjọba yóò gbógunti ìwà àjẹbánu

Adio ṣalaye pe Aarẹ Muhammadu Buhari ni lati akoko yii lọ, gbogbo eeyan ati ile iṣẹ ti wọn ba n ṣiṣẹ fun ijọba gbọdọ mọ pe gbogbo eeyan lo lanfaani lati ri bi ijọba ti n sanwo fun wọn.

Aarẹ Buhari rọ gbogbo ijọba ipinlẹ ati ti ibilẹ lati fi ijọba apapọ ṣe awokọṣe pe kawọn naa bẹrẹ iru eto yii.

Ọgbẹni Adio ni o ti di dandan fun gbogbo ẹka ijọba apapọ lati maa ṣe atẹjade bi wọn ṣe n sanwo sita lojoojumọ bẹrẹ lati miliọnu marun un lọ soke.

Bakan naa, wọn ni lati maa ṣe agbejade eto inawo wọn loṣooṣu ati gbogbo nnkan miiran ti wọn ba ṣe.

Adio fikun ọrọ rẹ pe ọga agba oluṣiro owo ni Naijiria naa gbọdọ maa ṣe atẹjade bi owo ṣe n wọle si apo ijọba ati bi owo ṣe n jade lojoojumọ.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ti gboṣuba kare fun Aarẹ Buhari lori agbekalẹ eto ti yoo maa ṣamojuto bi owo ti n wọle ati bi owo ti n jade lapo ijọba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSilas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe

Ti o ba fẹ mọ iye to n wọle sapo ijọba ati bi wọn ṣe n na owo naa, kan si oju òpó yii:

https://opentreasury.gov.ng/

Alukoro fẹgbẹ oṣelu naa, Lanre Issa-Onilu sọ pe eto naa yoo gbogun ti iwa ajẹbanu lawọn ile iṣẹ ijọba.