Christmas: Ọlọ́pàá gbẹ́sẹ̀ lé yínyin ohun ìṣiré ọdún ní ìpínlẹ̀ Ondo

Isire tannatanna Image copyright Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ẹnikẹni to ba yin ohun iṣire ọdun ti a mọ si banga nipinlẹ Ondo lasiko pọpọsinsin ọdun keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna yoo rugi oyin.

Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Adie Udie lo gbe ofin yii kalẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni ẹnikẹni to ba ta felefele to si tapa si aṣẹ yii yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.

Bakan naa lo ni gbogbo awọn to ba ṣowo ohun iṣire naa lasiko ọdun ti ọwọ ba tẹ ko ni ṣai jo lamba ofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTaa gan ló ń jí orin àti ohùn ara wọn lò nínú Adewale Ayuba àti Ajebori

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ṣalaye pe agbepolaja nikan kọ lole, ẹni gba a silẹ gan an ole ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo wa fi kun un pe awọn ṣe tan lati pese abo to peye lasiko ọdun to wọle de naa.