Catholic Church: A kò ní bó àṣírí àlùfáà tó bá bá ọmọdé lòpọ̀ mọ́

Pope Francis (June 2019 file picture) Image copyright Reuters

Poopu Francis ti wọgile dida aṣọ aṣiri bo alufaa ti wọn ba fi ẹsun ibalopọ kotọọ kan ninu ijọ Aguda.

Lati le mu iyatọ ba bi ijọ Aguda ti ṣe n fọwọ mu awọn ẹjọ to ni ṣe pẹlu ibalopo ọmọde ni wọn ṣe mu iyipada ofin yi wa.

Poopu mimọ sọ pe awọn ko ni ṣe amulo ofin yi mọ, paapa julọ fawọn ẹsun to niiṣe pẹlu nini ibalopọ pẹlu ọmọde ki idajọ to dara ba le waye lori rẹ.

Ohun ti igbesẹ yi tumọ si ni pe awọn to ba ke gbajare ẹsun ibanilopo yoo ni aanfaani lati sọrọ sita.

Loṣu keji ọdun ni awọn olori ijọ Aguda pe fun iyipada ofin yi lasiko ipade apero wọn.

Poopu sọ pe awọn ko ni i fi aṣiri gbogbo akọsilẹ ti wọn ba gbọ nipa ifipabanilopọ naa, ti wọn yoo si gbe igbesẹ otitọ, ati aabo fun awọn ti wọn ba balopọ.

Bakan naa ni Poopu sọ pe ''pe awọn ọmọ igbimọ ijọ naa gbọdọ tẹle ofin ilu, wọn si gbọdọ ran awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ lọwọ lati ṣe iwadii ti iṣẹlẹ yii ba waye.

Ofin daṣọ aṣiri bomi yi jẹ eyi to maa n daabo bo bi wọn ti ṣe n ṣe iṣakoso ijọ Aguda.

Iwe iroyin ijọ Aguda ṣe apejuwe ofin naa bi eyi ti tawọn ileeṣẹ n lo lati fi daabo bo ara wọn tabi eyi ti awọn to di ipo ijọba mu naa n lo.