Buhari: Baba 'Go slo' ní ìṣèjọba alágbádá ti ń falẹ̀ jù fún ipinnu òun gbogbo

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright @MBuhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣalaye pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ eto iṣejọba tiwantiwa ti pọ ju fun oun.

Lasiko ti awọn eeyan kan fi wa ba a ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to ti pe ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin ni ile aarẹ l'Abuja lo sọ bẹẹ.

Aarẹ Buhari ṣakawe eto igbogun ti iwa ijẹkujẹ to gbe dide lasiko iṣejọba rẹ gẹgẹ bii olori ologun lọdun 1983 si 1985 pẹlu ti asiko to wa yii gẹgẹ bii aarẹ alagbada, lẹyi to ni oun ti kẹkọọ pe iyatọ nla gbaa lo wa nibẹ.

Ọpọ awọn oloṣelu ni Ọgagun agba Buhari sọ sinu ẹwọn lẹyin oṣu diẹ to ditẹ gbajọba gẹgẹ bi ologun lọwọ ijọba alagbada nigba naa labẹ aarẹ Shehu Shagari.

Aarẹ Buhari ni oun ranti pe ni waranṣeṣa ni oun ko awọn oloṣelu ti oun funrasi pe igbe aye wọn pọ ju iṣẹ ọwọ wọn nigba naa sẹwọn nipasẹ awọn igbimọ gbogbo ti oun gbe kalẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya

Amọṣa, o ni oun naa gba ẹsan eyi nigba ti wọn yẹ aga mọ oun naa nidi nitori wọn fi panpẹ ofin mu oun naa wọn si sọ oun sinu ẹwọn.

Buhari ni ireti oun ni pe iṣejọba tiwantiwa yẹ ko tubọ jafafa ju ti ologun lọ amọṣa oun gan an lo wa falẹ ju.

Image copyright @MBuhari