Kano couple: Bí ìyàwó mi ẹni ọdún 84 bá bí ìbejì, Hussaina ati Hassana la ó sọ wọ́n

Aworan tọkọtaya Muhammad ati Fatsuma nilu Kano
Àkọlé àwòrán ''Bí ìyàwó mi ẹni ọdún 84 bá bí ìbejì, Hussaina ati Hassana la ó sọ wọ́n''

Ọrọ ifẹ ti ẹ ri yẹn, ko yọ ọmọde ko yọ agba silẹ.

Ohun lo difa fun Baba arugbo ẹni ọdun mẹ́rìnléláàdọ́rin kan ti o ṣalabapade iya ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin tawọn mejeeji si fẹra wọn sile.

Bii kayeefi lọrọ naa n ṣe ọpọ awọn eeyan ilu Kano ti iṣẹlẹ naa ti waye, amọ lọkan awọn ololufẹ mejeeji, awo ti rawo lọrọ ifẹ wọn ti wọn si ni ko si onya kan ti yoo ya awọn.

Igbeyawo Muhammadu Liti ati Fatsuma ti pe ọsẹ meji ti wọn si wa ni ipele faaji tọkọtaya ti oloyinbo n pe ni ''Honey moon''

Nigba ti wọn bere lọwọ Fatsuma bi o ti ṣe yofẹ fun Muhammadu, pẹlu ẹrin lẹnu, o sọ pe ''O maa n mu ẹbun orisirisi wa bami nibi ti mo ti n ta akara''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

''Awa mejeeji a maa ṣaaba ba ara wa jiyan ṣugbọn nigba ti ifẹ wọ inu ọrọ yi, niṣe la gbagbe gbogbo iwọn yẹn''

Muhammadu ni iyawo mẹta nile ṣugbọn ọkan ninu wọn ti ṣalaisi ti Fatsuma si ti gba ipo rẹ

Ki lawọn mọlẹbi ati ọrẹ sọ?

Fatsuma sọ pe nigba tawọn pinnu lati jẹ tọkọ taya, niṣe lawọn eeyan bẹrẹ si ni gbin erokero sawọn ọmọ wọn lọkan ni ireti pe wọn yoo tako ifẹ wọn.

''Ori ba wa ṣe wi pe ọmọ mi obinrin to dagba julọ, Maimuna gbaruku tiwa bẹẹ naa si ni abikẹyin mi, Aminat''

Lọpọ igba, Muhammadu yoo ṣabẹwo si Fatsuma ti yoo si maa kọ orin ifẹ sii niṣoju awọn ọmọ rẹ.

Koda, asiko abẹwo rẹ a maa ṣe deede igba ti afẹsọna ọmọ Fatsuma naa ba wa wo o.

Nigba takọroyin wa beere lọwọ Muhammad boya awọn ọmọ rẹ tako ajọṣepọ ohun ati Fatsuma, o ni ''koda awọn ọkunrin inu wọn dawo fun oun lasiko tawọn fẹ ṣe iyawo''

Fifẹ iyawo to ju ẹyọ kan lọ kii ṣe nkan ajoji lagbegbe ariwa Naijiria paapaa ni ẹsin Islam ti awọn mejeeji jọ n sin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Wọn beere lọwọ Fatsuma pe ṣe yoo wu u ki o bi ọmọ. Niṣe lo fi tayọtayọ dahun pe yoo dun mọ ohun ninu ti 'oun o si kọ lati bimọ pupọ.'

Muhammadu ninu esi ti rẹ si ibeere naa sọ pe bi Ọlọrun ba fi ọmọ ibeji ta oun lọrẹ, Husaaina ati Hassana loun yoo sọ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'