Trump Impeachment: Ààrẹ Trump n fẹ́ kí ilé aṣòfin gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ní kíákíá

Dinald Trump Image copyright Getty Images

Aarẹ orilẹ Amẹrika ti wọn yọ nipo, Donald Trump ti sọ pe oun fẹ ki ile aṣofin agba orilẹ-ede naa ṣe igbẹjọ oun ni kiakia.

L'Ọjọru ni wọn fi ọwọ osi juwe ile fun Trump, ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu Democrat kọ lati bẹrẹ igbẹjọ rẹ nile aṣofin agba.

Ẹgbẹ oṣelu Democrat gbe igbeṣẹ yii lẹyin ti wọn ni ile aṣofin agba naa ko ni ṣe igbẹjọ to ye kooro, nitori pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ti Trump jẹ ọkan lara wọn lo pọju nibẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican nile aṣofin naa pọ to de bi pe o ṣeeṣe ki wọn dibo gbe Trump lẹyin.

Iyọnipo aarẹ ọhun ti da awuyewuye silẹ ni ilu Washington.

Ẹsun ti wọn fi kan Trump ni pe pe o gbiyanju lati fi dandan mu orilẹ-ede Ukraine ko lee kede iwadii ọkan lara awọn alatako rẹ lẹgbẹ oṣelu Democrats, Joe Biden ati ọmọ rẹ Hunter.

Wọn ni o tun di ile aṣofin lọwọ iṣẹ nipa kikuna lati fọwọsowọpọ pẹlu ile naa nigba ti wọn ṣewaadi ọrọ naa.

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Àwọn ìbéèrè tó ṣàlàyé ohùn tó fẹ mọ nípa bi wọ́n ṣe ń yọ ààrẹ nípò l'Amẹrika

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn oluwọde ni New York n lọgun ki wọn yọ Trump nipo loru ọjọ idibo lati yọ Trump

Awọn to n fọkan ba iyọni nipo aarẹ Trump ti n beere ọrọ nipa ohun to le tẹyin iṣẹlẹ yi wa.

Njẹ ẹyin naa ti n ronu nipa kini o le ṣẹlẹ si Trump lẹyin ti wọn ba ribi yọ nipo abi?

Ẹ jẹ ki a jijọ ṣagbeyẹwo diẹ́ lara awọn ibeere to jẹyọ.

Nigba wo ni wọn yoo gbẹjọ rẹ nile aṣofin agba?

Wọn ko sọ pe dandan igba kan ni yoo jẹ amọ eleyi to fẹ sumọ igba ti yoo jẹ ni asiko tawọn aṣofin ba wole pada lẹyin isinmi loṣẹ keji inu oṣu kini ọdun to n bọ.

Asiko yi ni olori ọmọ ile to kere ju labẹ ẹgbẹ Democrat Chuck Scumer beere fun.

Bi o ti lẹ jẹ pe akẹgbẹ rẹ ninu ẹgbẹ Republican to jẹ olori ile aṣofin agba Mitch McConnel ko fi taratara gba ti asiko yi gẹgẹ bi igba ti wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ Trump,o ṣeeṣe ki o pada faramọ.

Image copyright Getty Images

Ipa wo ni igbẹjọ yi yoo ko lori erongba ati du ipo aarẹ lọdun 2020 fun Trump?

Ibeere nla re e ti ko si si ẹni to mọ esi rẹ bayi.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Republican ni igbẹjọ yi jẹ anfaani fawọn lati le gbaruku ti aarẹ to si tun jẹ kawọn pawọpọ da owo jọ fun ipolongo aarẹ Trump .

Ṣugbọn ni tawọn Democrats wọn ni abawọn leleyi yoo jẹ lasiko tawọn eeyan ba fẹ dibo fun Trump gẹgẹ bi aarẹ.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán The start of a key day in the House of Representatives

Esi awọn ibo abẹle kan ṣafihan pe ero ṣe ọtọọtọ laarin awọn to fẹ Trump ati awọn alatako r.

Ohun ta le sọ ni pe ko si ẹni to le sọ ibi ti idibo aarẹ yoo fi si ṣaaju igba ti wọn yọ Trump.

Bayi ti wọn yọ, ko sẹni to le sọ ibi ti yoo ja si.

Ti wọn ba yọ Trump ti igbakeji rẹ Pence di aarẹ toun naa wa yan Trump ni igbakeji ti Pence si tun wa kọwe fipo silẹ nkọ?

Ko si nkan to tako igbesẹ yi ninu iwe ofin Amẹrika, fun idi eyi, o ṣeeṣe bẹ.

Amọ ipenija akọkọ ti Pence yoo koju ki o to le yan Trump sipo igbakeji ni pe awọn ọmọ ile aṣojuṣofin yoo ni lati buwọlu iyansipo yi.

Image copyright Getty Images

Ti a ba woye pe awọn ọmọ ile aṣojuṣofin yi naa ni wọn fẹ ya Trump ni po,ko daju pe wọn yoo buwọlu iyansipo rẹ gẹgẹ bi igbakeji aarẹ lẹyin ti wọn ba yọ tan.

Nkan mii to ṣeeṣe ki o waye ni pe awọn ọmọ ile aṣofin agba le daba lasiko ti wọn ba n dibo ki Trump fipo silẹ pe ki o ma le di ipo miran mu lọjọ iwaju.

Bi ọrọ ba rii bẹ,Trump o ni ribi pada sipo koda ti Pence ba yan ni igbakeji.

Amọ ti wọn ko ba daba pe ko ma di ipo miran mu lọjọ iwaju,ko le si nkankanti yoo di lọwọ lati du ipo aarẹ lọdun 2020 ti o si le pada sile ijọba White House.

Ti ile aṣofin ko ba ni dibo yọ Trump,ki wa lo mu wọn bẹrẹ igbesẹ iyọni nipo yi gaan fun?

Ti eeyan ba gbọrọ tawọn Democrats n sọ,wọn ni lootọ ni pe awọn le ma ri Trump yọ ṣugbọn ohun to ṣe koko fawọn ni pe ki o kawọ pẹyin rojo ẹsun ti wọn fi kan.

Wọn ri iwa ti aarẹ Trump hu pẹlu bi o ti ṣe beere iranwọ lọdọ aarẹ Ukraine gẹgẹ bi aṣilo ipo fun imọtaraẹni nikan.

Bẹẹ naa si ni ọrọ tawọn eeyan n sọ pe lati ibẹrẹ ijọba Trump lawọn Democrats ti n pariwo ki wọn yẹ aga nidi rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Trump Impeachment: Báyìí ni wọ́n ṣe ń yọ ààrẹ nípò lórílẹ̀-èdè Amẹrika

Wọn ti yọ Donhald Trump nipo gẹgẹ bi aarẹ orilẹ-ede Amẹrika ṣugbọn, ọrọ ko tii tan sibẹ.

Eredi ni pe iyọnipo ọhun si ku abala kan, leyi to wa lọwọ ile aṣofin agba orilẹ-ede ọhun nitori ọna meji ni yiyọ aarẹ nipo lorilẹ-ede Amẹrika pin si.

Orumọju ni wọn pari abala kinni, ni ibi ti wọn ti fi ẹsun kan an pe, o ṣi ipo rẹ lo gẹgẹ bi aarẹ ti wọn si fi ọwọ osi juwe ile fun un.

Abala keji yoo waye losu kinni, ọdun 2020, nibi ti ile aṣofin agba ni Washington yoo ti ṣe igbẹjọ rẹ boya o jẹbi ẹsun ti wọn fi yọọ nipo.

Ninu abala keji yii, ida meji ninu mẹta ni yoo ṣafihan boya wọn yoo le Trump kuro lori alefa patapata.

Ṣugbọ lọwọ yii, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ti Trump jẹ ọkan lara wọn lo n dari ile aṣofin agba ilẹ Amẹrika, leyi ti yoo mu ki yiyọ aarẹ Trump ṣoro diẹ.

Ibi ti ọrọ de duro bayii ni pe, boti lẹ jẹ pe wọn ti yọ Trump nipo, oun si ni aarẹ titi di igba ti ile aṣofin agba yoo ṣe idibo tiwọn.

Wọ́n ti yọ Donald Trump nípò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò tíì tán síbẹ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Ki lo ti ṣelẹ sẹyin?

Trump Impeachment: Ilé aṣojú-ṣòfin Amẹ́ríkà dìbò yọ Donald Trump nípò ààrẹ

Wọn ti yọ Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump nipo.

Donald Trump ni Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika kẹta ninu itan ti ọbẹ yoo maa ba nidi lati ọdọ awọn ile aṣoju-ṣofin lorilẹ-ede naa.

Igbesẹ yii ti wa sọ ọ di ọrọ kannakanna na ọmọ ẹga bayii nigba ti ijiroro lati buwọlu iyọnipo naa ba waye ni ile aṣofin agba nibẹ.

Ẹsun meji to da lori aṣilo ipo, ati ṣiṣe idiwo fun iṣẹ ile aṣofin-ni wọn fi kan Aarẹ Donald Trump .

Idibo lori ẹsun meji yii ko ṣai ba ilana ẹgbẹ oṣelu lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idibo yii yoo fidi mulẹ bi awọn aṣofin agba ba dibo sapa kan naa lori rẹ.

Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrats yatọ si meji lo dibo fun yiyọ Trump nipo, bẹẹni awọn Republicans to jẹ ẹgbẹ oṣelu Trump dibo tako o.

Wakati mẹwaa gbako ni ijiroro lori ọna ti ilana iyọnipo naa yoo gba fi waye laarin awọn aṣofin naa gba ni Amerika.

Ni nnkan bii agogo meji abọ oru oni to jẹ agogo mẹjọ abọ alẹ lorilẹ-ede Amẹrika ni wọn bẹrẹ idibo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

Ẹsun aṣilo ipo ti wọn fi kan aarẹ Trump da lori ẹsun pe o gbiyanju ati fun orilẹ-ede Ukraine lokun lọrun ki o lee kede iwadii ọkan lara awọn alatako rẹ lẹgbẹ oṣelu Democrats, alagba Joe Biden.

Ẹsun keji to kọ Trump lẹsẹ ni pe o di ile aṣofin lọwọ iṣẹ nipa kikuna lati fọwọ sowọpọ pẹlu ile naa lori eto iwadii ati yọ aarẹ naa nipo pẹlu pipaṣẹ pe awọn eeyan kan ko maṣe farahan lati jẹri niwaju ile naa.

Igba o le ọgbọn, 230 awọn aṣofin lo dibo ki wọn yọ ọ lori ẹsun aṣilo ipo ti awọn mẹtadin ni igba, 197 si ta ko o.

Igba o le mọkandinlọgbọn lo dibo fun yiyọ Trump labẹ ẹsun pe o di ile aṣofin lọwọ ti awọn mejidin ni igba si ta ko o.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Pẹlu iyọkuro nipo rẹ yii, Donal Trump ti di sawawu kan naa pẹlu awọn aarẹ meji miran to ti jẹ ri nilẹ Amẹrika ninu itan orilẹede ọhun.

Andrew Johnson ati Bill Clinton ni wọn ti dibo yiyọ nipo ri fun.

Eyi ti fa ijiroro ati igbẹjọ gbogbo di iwaju awọn aṣofin agba lorilẹ-ede naa lati mọ boya lootọ, Trump yoo fi ipo silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'