Ikorodu muder: Awọn ọlọpaa ni awọn yoo bẹrẹ iwadii lori iku rẹ

Mutiu Agbọnṣaṣa Image copyright Mutiu Agbọnṣaṣa/facebook
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpaa ni awọn yoo bẹrẹ iwadii lori iku rẹ

Lẹyin ọdun marundinlaadọta to lo loke okun gẹgẹ bii agba oluṣiro owo ni ilu New York lorilẹ-ede Amẹrika, alagba Mutiu Agboṣaṣa dari wale lati wa sinmi iṣẹ ki o lee gbadun oogun rẹ.

Amọṣa awọn ẹni ibi bẹẹ wo pẹlu iku lẹyin bii oṣu mẹta to gunlẹ si ilu Ikorodu nibi to n gbe.

Iroyin sọ pe ile igbafẹ Island club ni alagba naa ti de nibi to ti lọ ba awọn ọrẹ rẹ ṣe faaji lawọn eeyan kan ti wọn fura si gẹgẹ bi agbenipa kọ luu.

Wọn ṣaa si wẹlẹwẹlẹ lẹyin ti wọn yinbọn fun un, wọn si gbe oku rẹ sọ sinu ọkọ kan ki wọn to dana sun un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti mu ẹṣọ ile oloogbe naa to wa ni Ginti Estate, lagbegbe Ijede, ni Ikorodu.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita ṣalaye pe Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Hakeem Odumoṣu ti paṣẹ iwadii to jinlẹ si iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfrica Eye: Ohun tí ọ̀rẹ́ mi fí sórí 'Social Media'ló wọ̀ mí lójú- Grace

Gẹgẹ bi atẹjade ọlọpaa ṣe sọ, nnkan bii agogo meji abọ oru ni ọjọ Aiku, ni ẹṣọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Rohis Adamu Dana de agọ ọlọpaa lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti.

Image copyright Mutiu Agbosasa/facebook

Gẹgẹ bi atẹjade ọhun tun ṣe fi sita, ẹṣọ oloogbe Agboṣaṣa ni nnkan bii agogo mẹwaa abọ ọjọ Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu kejila toun ṣi geeti fun ọga oun lati wa ọkọ wọle ni awọn ọkunrin mẹrin kan ṣa deede ya wọ ọgba bi oun ti ṣe fẹ maa tii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOndo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

O ni pe ṣa deede ni oun gbọ ti ọga oun n pariwo si oun pe ki oun lọ pe awọn ọlọpaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil