LASEPA: Wo àwọn ohun tí o le ṣe tí yóò mú ọ rugi oyin òfin ariwo pípa l'Eko

Oṣiṣẹ LASEPA kan n gun ori ile kan

Oríṣun àwòrán, @LasepaInfo

Àkọlé àwòrán,

Wo àwọn ohun tí o le ṣe tí yóò mú ọ rugi oyin òfin ariwo pípa l'Eko

Ajọ to n mojuto ọrọ ayika ni ipinlẹ Eko, LASEPA ti ṣi ile ijọsin ati ile itura mẹrindinlọgbọn kan ti wọn ti pa tẹlẹ fun titapa si ofin to de eto ayika, paapaa julọ ariwo apọju layika ni Eko.

Bakan naa ni LASEPA tun paṣẹ fun awọn ṣọọṣi meji miran pe ki wọn ko ijọsin wọn kuro lagbegbe ti wọn wa lọwọlọwọ nitori apọju ariwo to n ṣe akoba fun adugbo ti wọn wa.

Ọga agba ajọ LASEPA, Ọmọwe Dọlapọ Faṣawẹ ṣalaye pe ajọ naa yoo maa mojuto bi awọn eeyan ati ileeṣẹ fi n tẹle ofin to de ayika ni ipinlẹ Eko.

O ni paapaa lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii, ohun ti ijọba n fẹ ni ayika to gbadun fun araalu. Nitori naa ni ajọ naa yoo fi tubọ tẹpa mọ iṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Mobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Bakan naa lo sọrọ nipa awọn igbesẹ ti ile ati ajọ gbọdọ gbe lati bọ lọwọ paṣan ajọ LASEPA.

Ofin to de ariwo pipa ni ilu ti ipinlẹ Eko la awọn igbesẹ to yẹ kalẹ ni ọkọọkan awọn abala rẹ.

Àkọlé fídíò,

Ondo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

Diẹ lara awọn igbesẹ to yẹ ni gbigbe niyi:

Gbogbo eto, ilee igbafẹ bii hotẹẹli, ile ijo ati awọn ile ijọsin gbọdọ gba iwe aṣẹ ariwo.

Ẹṣẹ si ofin ni ki ẹnikẹni maa tan orin ni ita gbangba tabi lilo awo orin tabi ohun eelo orin ati ẹrọ gbohungbohun ni gbangba.

Ẹṣẹ si ofin ni lati lo ẹrọ gbohungbohun fi kede tabi polowo ohunkohun ni itagbangba lawọn agbegbe ti araalu n gbe.

Ẹṣẹ si ofin ni lati lo ẹrọ gbohungbohun fi pe ero sọkọ ni awọn ibudokọ ero, ọja ati ita gbangba.

Ẹgbẹ tabi ajọ kankan ko gbọdọ lo ẹrọ gbohungbohun ti ko ni jẹ ki raalu ri eti gbọran lati tan iroyin, ẹsin tawọn ariwo miran lai gba aṣẹ lọwọ ajọ to yẹ.

Oríṣun àwòrán, @LasepaInfo