Mohammed Adoke: EFCC dájọ́ wíwà láhàmọ́ ọjọ́ mẹ́rìnlá fún Mínísítà ètò ìdájọ tẹ́lẹ̀

Mohammed Adoke

Oríṣun àwòrán, OTHER

Adajọ agba orilẹede Naijiria, Mike Ozhekome to tun jẹ agbẹjọro fun Agbẹjọro -Agba Naijiria tẹlẹ ri Mohammmed Adoke ti ta abuku ajọ EFCC lori pe wn fi panpẹ mu onibara rẹ.

O jẹ ko di mim pe wn ti kọkọ gbe Adoke l si ile ẹjọ lẹyin rẹ gan iyẹn nigba to n kawe lati gboye Masters ni Netherlands.

Ninu iwe to fọwọ si lọjọ ẹti, o ni gbigba aṣẹ ile ẹjọ lati fi Ọgbẹni Adoke si ahamọ fun odidi ọsẹ meji gbako ko tọ rara.

O ni "ki wa ni wọn fẹ fi kiko o ni papamọra yii ṣe, ṣe lati fi tẹ ẹ ri ni, fi iya jẹ ẹ, da a laamu ninu ọpọlọ tabi lara"? O sọ eyi nitori ailera rẹ.

Nitori naa adajọ agba fun pe si EFCC lati gba beeli agbẹjọro agba tẹlẹ ri ko le lọ tọju ara rẹ tori o ni ohun to gbe e lọ si ilu Dubai naa ni ọrọ ilera.

Ẹwẹ o ni bi wọ́n ba kọ ti wọn o ba gbọ, wọn yoo mu awọn lọranyan lati fi ọna ofin kọ aṣẹ wọn o.

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja lo fun ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, ni aṣẹ lati fi Agbẹjọro -Agba Naijiria, to tun jẹ Minisita fun eto idajọ, Mohammed Adoke si ihamọ fun ọjọ mẹrinla.

Onidajọ Othman Musa lo fun EFCC ni aṣẹ yii nitori iwe ẹbẹ ajọ naa ti agbẹjọro rẹ, Fatima Mustapha fun ile ẹjọ l'ọjọ Ẹti.

Mustapha sọ pe erongba lati fi Adoke si ihamọ yoo fun wsn ni asiko lati pari iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Adoke n koju ẹsun pe e o mọ nipa kiko owo kan to ni i ṣe pẹlu iwe asẹ fun ileeṣẹ epo Shell ati ENI lọdun 2011. Owo naa le ni biliọnu kan Dọla (1.3bn).

Ilu Abuja ni wọn ti mu u Adoke l'Ọjọbọ to pada si Naijiria lẹyin to ti salọ si ilẹ okeere fun ọdun mẹẹrin ni EFCC mu.

Loṣu Kẹwa ọdun ni ileeṣẹ ọlọpaa agbaye, Interpol gba Adoke mu u ni Dubai lori ipa to ko ninu apapin owo epo rọbi ti a mọ si Malabu Oil Deal.

Àkọlé fídíò,

'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Ajọ EFCC sọ pe ọga ileeṣẹ awọn, Ibrahim Magu ati awọn alaṣẹ Dubai ti ṣe ọpọlọpọ ipade lori agbẹjọro agba Naijiria tẹlẹ naa.

Lati ọjọ kọkanla oṣu Kọkanla ni Adoke ti wa ni ahamọ ni Dubai nigba ti agbẹjọro rẹ Mike Ozekhome sọ fawọn akọroyin pe o lọ gba itọju.

O sọ pe ile ẹjọ Naijiria ti ṣaaju ni Adoke ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ati pe dide to pada de si Naijiria yii, yoo lọ yanju ara rẹ lọdọ awọn to yẹ.

Mohammed Bello Adoke ni Minisita feto idajọ labẹ ijọba Goodluck Jonathan laarin ọdun 2010 si 2015.