Wòlíì bá obìnrin 300 lò pọ́, ó gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọ́dún 19

Aworan wolii Joao Teixeira de Faria

Oríṣun àwòrán, AFN/GETTY IMAGES

Palaba wolii eke kan to pe ara rẹ ni Johannu inu bibeli 'John of God' ti ṣegi ti adajọ si ti dajọ ẹwọn ọdun mọkandilogun fun un lori ẹsun ibalopọ pẹlu awọn obinrin to le ni ọọdunrun lọna aitọ.

Idajọ yii ko ṣẹyin bi awọn obinrin kan to fi mọ ayaworan ọmọ orileede Zahira Leeneke Maus ṣe fẹsun kan pe o fi ọna aitọ ba wọn laṣepọ.

Joao Teixeira de Faria, tawọn eeyan mọ si "John of God", ni adajọ sọ pe o jẹbi ifipabalopo awọn obinrin meji ti o si laṣepọ lọna aitọ pẹlu awọn meji miran ni ile iwosan rẹ to wa ni Abadiania.

Agbẹjọro ọgbẹni Texeiria sọ pe awọn yoo tako idajọ yi toun ti pe awọn ẹsun miran ṣi wa nilẹ́ ti wọn fi kan an.

Yatọ si awọn ti a ka kalẹ, awọn obinrin ọmọ Brazil mẹsan kan ti wọn ni ki wọn fi orukọ bo awọn laṣiri naa naka si i pe o fi ọna eburu ba wọn laṣepọ.

Ni kete ti iroyin lu sita ni ibẹrẹ oṣu Kejila ni awọn agbofinro ti kede pe awọn n wa Teixeria.

Iwe iroyin O Globo ni Brazil naa sọ pe awọn alaṣẹ fura si ipe o fẹ na papa bora nigba ti o gba owo to to miliọnu dọla mẹjọ lakoto owo rẹ meloo kan.

Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, Joao Teixeira de Faria jọwọ ara rẹ fawọn agbofinro to si sọ ninu fọnran fidio kan pe ''mo jọwọ ara mi fun idajọ agbara to gajulọ ti mo si mu ileri ṣẹ lati fi ara mi fun awọn to n ṣe idajọ orilẹ aye.''

Ọgbẹni Teixeria ti kii ṣe onimọ iṣegun ni wọn ti ṣaaju ni ko san owo itanran ti o si ṣẹwọn tori pe o n ṣe itọju awọn eeyan lai ni iwe aṣẹ.

Lọdun 2013, Oprah Winfrey ṣabẹwo si ile iwosan rẹ nibi to ti ri to n ṣe iṣẹ abẹ lai lo irinṣẹ abẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ iroyin ABC News sọ, Ọgbẹni Faria sọ pe ẹmi Dokita ọgbọn ati awọn ẹmi miiran lo ma n wọ inu ara ohun ti a si maa fun oun lagbara lati ṣe iwosan fawọn eeyan.