Fayose: Mí ò ní èsìí fọ̀ f'áwọn tó ní mo dánìkàn ta ilẹ̀ ẹgbẹ́ PDP ní Ekiti

Aworan Fayose

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lere Olayinka

Gomina ana nipinlẹ Ekiti Ayodele Fayose ti fesi si ẹsun ti alaga ẹgbẹ nipinlẹ naa fi kan an pe o danikan ta ilẹ̀ ẹgbẹ fọkan lara awọn wọlewọde rẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti BBC ni pẹlu agbẹnusọ rẹ Lere Olayinka, Fayose sọ pe ija lo de lorin dowe lo mu ki awọn to n ba oun lorukọ jẹ fẹsun bẹẹ kan oun.

Olayinka sọ pe agba ẹgbẹ PDP ni Fayose nitori naa ko si iru ọrọ ti ara rẹ kọ.

''Ninu oṣelu Naijiria, agba ọjẹ ni Fayose jẹ. Agba kii si ya ẹnu. Nitori naa a ko ni ba awọn to n tabuku ba wa takurọsọ''

Olayinka tẹsiwaju pe lati fi iwe ẹri ibi ti Alaga ẹgbẹ ati akọwe ẹgbẹ ti buwọlu iwe pe awọn gba owo ilẹ ti ẹni to ra lọwọ ẹgbẹ da a pada si akoto owo ẹgbẹ PDP ni ilu Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Lere Olayinka fi kun ọrọ rẹ pe ti ina ko ba ti lawo, kii jo kọja odo eleyi to tumọ si pe awọn kan ni wọn n ru ina si bi ọrọ yii ṣe di fa kin fa.

Ninu ọrọ tirẹ, alaga ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Ekiti ti a ri pe o buwọlu iwe ti Lere Olayinka fi sọwọ si wa sọ pe ayederu iwe ni Fayose n gbe ka ati pe ohun ko buwọlu iwe kankan.

O ni Fayose nikan lo da ta ilẹ naa fun wọlẹwọde rẹ ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ ko si mọ nipa rẹ.

''Lootọ ni Fayose wa ba mi ki n buwọlu iwe kan ṣugbọn mo sọ pe mi o le buwọlu nitori yoo dabi pe mo n fi ọbẹ ẹyin jẹ ẹgbẹ PDP niṣu ni''

O tẹsiwaju pe ''A ko tii ta olu ileeṣẹ ẹgbẹ wa. Eyikeyi iwe ti Fayose ba ni to ṣafihan pe a jijọ ta a ni, irọ pọnbele ni''

Laipẹ yii ni Gomina Fayose sọ pe ohun gba iyọnda awọn igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ ki ohun to ta olu ileeṣẹ ẹgbẹ PDP