Oyo PDP: Olórí ọ̀dọ́ farapa ni, ẹni tó wa ọ̀kọ́ ló kú

Aworan ọkọ ẹgbẹ oṣelu PDP Oyo ati ọmọ ẹgbẹ to d'oloogbe

Oríṣun àwòrán, PolyIbada/Facebook

Ọkọ to gbe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ipinlẹ Ọyọ to n bọ lati ibi idajọ ile ẹjọ giga julọ nilu Abuja eyi to gbe gomina Seyi Makinde leke ni ijamba, o mu ẹmi ọmọ ẹgbẹ kan lọ awọn mẹta mii si fara pa.

Nigba ti BBC Yoruba kan si alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ Alhaji Yemi Mustapha, o jẹ ko di mimọ lodi si awọn iroyin mii to sọ pe olori ọdọ ẹgbẹ lo ku pe irọ ni.

Àkọlé fídíò,

Ọrọ rè láti ẹnu àwọn Agbẹjọ́rò Makinde àti Adelabu nípa ìdájọ ọ́rọ́ ìdìbò Gómìnà Oyo

Asiwaju Adekola Adeoye ni olori ọdọ ẹgbẹ to jẹ kan lara awọn to farapa ninu ijamba kọ naa to si ti n gba itọju nile iwosan.

Yemi Mustapha ṣalaye pe arakunrin naa, Yemi Adeniran lo wa ọkọ ti wọn wa ninu rẹ ti wọn n gbe bọ lati Abuja wọn si ti baba wọ inu ilu Ibadan nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.

O ni ko sẹni to ku ninu awn adari ẹgbẹ ẹni to si ku yii kii ṣe ọkan lara awọn adari ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò,

Ankara Design: Ai ri oníbara ló jẹ́ kí n wá ọ̀gbọ́n àtinúdá tèmi.

Alaga ẹgbẹ ni oun tabi gomina ko si ni ilu Ibadan nigba ti o ṣẹlẹ ṣugbọn nkan ti wn ṣalaye fun oun ni pe taya ọkọ lo fọ lori ere, arakunrin naa lo si n wa ọkọ to wa jẹ pe ẹgbẹ ọdọ rẹ ni taya ti fọ.

Ẹwẹ, Yemi Mustapha ni kete ti awọn de ti wọn si n ṣe eto ati ki gomina ku abọ ati ku oriire ni awọn tun lọ si ile ẹbi oloogbe naa lati bẹ wọn wo.

Gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe, ẹgbẹ ni igbimọ eleto ilera tiwọn to ti sare ṣe asúgbàá awọn to farapa lọ si ile iwosan.

Oloogbe Yemi Adeniran ti gbogbo eeyan mọ si Likedat ti fi igba kan jẹ olori ẹgbẹ awọn akẹkọọ Naijiria (NANS) to si lorukọ laarin awọn ọdọ oloṣelu ni ilu Ibadan.