Mikel Arteta: Wọ́n ti kéde Mikel Arteta gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ Arsenal tuntun

Mikel Arteta

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Arteta ti sẹṣẹ gẹgẹ bi adari labẹ Pep Guardiola ni Manchester City

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti kede Mikel Arteta gẹgẹ bi akọnimọgba rẹ tuntun.

Ninu adehun iṣẹ naa, Arteta yoo dari ikọ Arsenal fun ọdun mẹta ati aabọ.

Idunu ati ayọ ni Arteta fi gba iṣẹ naa to si sọ pe "O jẹ iyi nla fun mi lati dara pọ mọ ikọ Arsenal."

O tẹ siwaju pe "Inu mi dun nitori Arsenal jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to tobi ju lagbaye."

Arteta ti n ṣe iṣẹ tẹlẹ gẹgẹ bi adari labẹ Pep Guardiola ni Manchester City lẹyin to darapọ mọ ikọ ọhun lọdun 2016.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogoji naa ti fi igba kan ṣe iṣẹ ni ikọ Arsenal yii ati ikọ Everton ri.

Awọn adari ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ko tii kede awọn ti yoo ba Arteta ṣeṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Ankara Design: Ai ri oníbara ló jẹ́ kí n wá ọ̀gbọ́n àtinúdá tèmi.