Infibulation: Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì

Obinrin to la idi silẹ

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

Asa adayeba ni ọpọ ilu ni pe o yẹ ki ọkọ iyawo tuntun ba aya rẹ nile, lai tii mọ ọkunrin kankan.

Amọ eyi ko ri bẹẹ mọ nitori ọdaju to de ile aye, ti awọn takọ tabo ti ko tii ni iyawo tabi ọkọ si maa n fi adun ifẹ da ara wọn lara ya.

Idi si ree ni ọpọ igba, ti ironu ati ipaya fi maa n ba ọpọ ọlọmọge to ti mọ ọkunrin amọ to n gbero lati lọ sile ẹkọ ni awọn ilu kan ti asa ibale ti gbinlẹ.

Ọpọ iru awọn obinrin yii si lo maa n wa ọna ti wọn yoo fi sọ ara wọn di ọmọge ti ko tii mọ ọkunrin lẹẹkeji lati gba ara wọn lọwọ itiju, idẹyẹsi ati ẹgan.

Koda, awọn ọmọge to ti jaye sẹyin, ti wọn si n fẹ ki ọk wọn gbagbọ pe awọn ko tii mọ ọkunrin, naa maa n dọgbọn si.

Àkọlé fídíò,

Èyí ni ìtàn bí ẹni tí mó gbọ́njú mọ̀ bíi bàbà ṣe fipá bá mi lájọṣepọ̀

Wo ọna tawọn obinrin n gba lati di ọmọge ti ko mọ ọkunrin ri lẹẹkeji:

Awon obinrin kan n lọ fun iṣẹ abẹ lati da abẹ fun'ra wọn, ti igbeyawo wọn ba ti ku oṣu kan tabi meji, ki wọn o le ro wi pe wundia ti ko ti i ni ibalopọ ri ni wọn.

Eyi n waye bo tilẹ jẹ wi pe ọpọ ninu wọn ni wọn ti dabẹ fun nigba ti wọn wa l'ọmọde.

Ni awọn orilẹede kan, nigba ti awọn ikoko ba wa ni ọsẹ kan si ọmọ ọdun mẹrin si mẹwa ni wọn maa n ṣe e.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn maa n ṣe eyi nipa gige idọ ati labia kuro. Ti wọn si ṣa ba maa n ran an pada lati le mu ki iho oju ara o kere si. Igbesẹ yii ni wọn n pe ni infibulation.

Awọn agbẹbi lo si maa n ṣe isẹ abẹ yii amọ awọn owu ti wọn fi ran oju ara naa yoo tu u ti obinrin ba ti ni ibalopọ.

Bawo ni inira isẹ abẹ abẹ́ dida ẹlẹẹkeji yii ti ri:

Ọkan lara awọn obinrin to ṣe e, Maha sọ fun BBC pe inira pupọ ni igbesẹ naa fa fun oun.

Maha ti a fi orukọ bo ni aṣiri ti le ni ogun ọdun, o si jẹ akẹkọọjade ni fasiti kan, bi o tilẹ jẹ pe ni ọpọ orilẹede lagbaye lonii, ofin ko fi aaye gba abẹ dida fun awọn ọmọbinrin.

"Isẹ abẹ naa dun mi pupọ, debi pe mo ni lati lọ duro si ọdọ ọrẹ mi kan fun ọpọlọpọ ọjọ titi ti ara mi fi ya nitori pe mi o fẹ ki iya mi o mọ pe mo ṣe e.

"O nira fun mi lati tọ. Bakan naa ni mi o le rin daada fun ọjọ diẹ."

Maha lọ fun iṣẹ abẹ naa nigbati o ku oṣu meji ti yoo ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin to ju u lọ diẹ.

Maha sọ pe "Ko ni i fi inu tan mi to ba fi mọ pe mo ti ni ibalopọ, ka to o ṣe igbeyawo wa."

"Niṣe ni yoo fi ofin de mi pe mi pe n ko gbọdọ maa jade tabi lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ."

Àkọlé fídíò,

Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Ọpọlọpọ aṣa lo n polongo pe ibale obinrin ṣe pataki ṣaaju igbeyawo, eyi si lo maa n mu ki awọn obinrin kan tun pada lọ tun awọ fẹlẹfẹlẹ to bo ẹnu iho oju ara wọn ṣe.

Ṣugbọn, kọọrọ ni wọn ti maa n ṣe iṣẹ abẹ 'oju ara tuntun yii', nitori pe ẹgbẹ awọn onimọ iṣegun oyinbo lawọn orilẹede kan tako o.

Ọkan lara awọn agbẹbi to maa n ṣe e sọ pe lootọ ni oun korira isẹ abẹ naa, ṣugbọn oun maa n ṣe ti oun ba nilo owo fun itọju awọn ọmọ ọmọ oun ti iya wọn ti ku.

Bo tilẹ jẹ wi pe ọlaju ti de, awọn obinrin kan si n ṣe e, nitori pe awọn ọkunrin kan maa n fẹ ki iyawo ti wọn yoo fẹ ẹ, jẹ omidan ti ko ni ibalopọ ri.