Disability: Kò sẹ́ni tó kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń fi ọwọ́ sọ̀rọ̀, ìmísí yẹn kàn wá ni - Tola

Disability: Kò sẹ́ni tó kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń fi ọwọ́ sọ̀rọ̀, ìmísí yẹn kàn wá ni - Tola

O ti pe ọ̀dun mejilelọgbọn. O ti balaga bayii, ẹnu ara rẹ si lo fi n sọ̀rọ̀ ní tirẹ bo tilẹ jẹ pe awọn obi rẹ di leti, Tola Amero ko ya odi ọmọ ni tirẹ.

Nigba ti BBC ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Tola, o ni "pé àwọn òbí mi ya odi, ó dà bíi pe'mo kẹ̀yìn sí àgbáyé ni".

Kini Tola ni o ṣokunfa eyi?

Idi ni pe o ni oun fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí rẹ to di létí.

Tola ni oun ni lati maa da ọpọlọpọ nkan ṣe funrarẹ lati kekere nigba ti ko si oluranlọwọ, awọn obi ti ko ba tun wu lati ṣe eyi ko lee gbọ debi ti wọn yoo le ṣe ohun gbogbo fun un.

"Ó ma ń dé ìpele kan tí mo ma fẹ́ fí ẹnu bá wọn sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n kò sí ṣíṣe kò sáàṣe. bi mo ba fẹ fi awọn obi mi mọ awọn ọrẹ́ mi, ipenija kan tun niyẹn".

Awọn eeyan a dẹ maa kaanu mi tori pe mo jẹ ọmọ obi to jẹ odi, o dẹ jẹ nkan ti mi o fẹran rara.

Mo jẹ́ ọmọ àwọn obi tó di létí ṣùgbọ́n kí n sọ òótọ́, ayé ò parẹ́ síbẹ̀.