Osun Politics: Aregbesola ní irọ́ n'ìròyìn tó ń sọ pé aáwọ̀ wà láàrín òun àti gómìnà Oyetola

Gomina Oyetọla ati Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla n ki ara wọn

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola

Gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun to ti di minisita fọrọ abẹle bayii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti ṣalaye pe ko si ija tabi aawọ kankan laarin oun ati gomina to wa nipo nibẹ bayii, Gboyega Oyetọla.

Arẹgbẹṣọla yannana ọrọ naa lasiko ti wọn n fi jẹ oye Amirul Wazirul Muminina fawọn musulumi ni ipinlẹ Ọṣun.

O ti pẹ diẹ bayii ti gbọyi-sọyi lẹnu awọn eeyan ti n lọ kaakiri, paapaa julọ laarin awọn ololufẹ oloṣelu mejeeji yii loju opo ayelujara pe tirela ti gba aarin awọn mejeeji lọ.

Aisi gomina Oyetọla nibi ayẹyẹ wiwe lawani naa lo tubọ mu ki ọpọ tun maa woye pe abi lootọ ni ọrọ ọhun ni.

Amọ ni kete ti asiko to fun un lati sọrọ ni Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla ti ti kọngọ bọ ilu ọrọ to si lu u laluye pe, aifara han Oyetọla nibi ayẹyẹ naa kii ṣe ti ija, bi ko ṣe irinajo rẹ si ilu Mẹka lati lọ ree tuuba fun Ọlọrun.

Arẹgbẹṣọla ni oun ati Gomina Oyetọla ṣi sọrọ ni owurọ ọjọ ayẹyẹ naa ati pe, ẹjẹ to ba Ọlọrun jẹ lasiko ti o fi n sare igbẹjọ idibo rẹ nile ẹjọ to ga julọ lorilẹede yii pe bi oun ba lee bori oun yoo lọ dupẹ nilẹ mimọ Mecca lo faa ti ko fi fara han nibẹ.

Àkọlé fídíò,

'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Lati igba ti igbesẹ ati yan oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fun eto idibo sipo gomina l'Ọṣun to waye lọdun 2018 ni gbọyi-sọyi ti n waye lori boya omi ọrọ laarin awọn mejeeji yii ṣi toro.

Gomina Oyetọla ni olori awọn oṣiṣẹ to ba Arẹgbẹṣọla ṣiṣẹ lasiko to fi wa ni ipo gomina ni ipinlẹ Ọṣun.