Immigration: Akẹ́kọ̀ọ́ méjì tó há sí ibùdó àtìpó ní Bosnia ti gúnlẹ̀ padà sí Nàìjíríà

Abia Uchenna ati Eboh Chinedu pẹlawọn to wa pade wọn ni papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, @nidcom_gov

Awọn akẹkọọ ọmọ orilẹede Naijiria tawọn agbofinro fi si ahamọ ni ibode Bosnia ti gunlẹ sorilẹede Naijiria.

Awọn akẹkọ meji ọhun ti orukọ wọn n jẹ Abia Uchenna, Eboh Chinedu atawọn mẹta miran ti wọn jẹ akẹkọ fasiti imọ ẹrọ FUTO to wa nilu Owerri nipinlẹ Anambra ni wọn lọ silu Zagreb tii ṣe olu ilu Croatia lati kopa ninu idije ere idaraya ẹyin ori tabili kan to wa laarin awọn akẹkọ Fasiti lagbaye.

Ọjọ kejila oṣu kọkanla ọdun 2019 ni wọn de ibẹ ṣugbọn ọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla kan naa ni awọn ọlọpaa gbe wọn nigba ti wọn ko lee mu iwe aṣẹ gbogbo to yẹ jade.

Eyi lo mu ki awọn ọlọpaa naa taare si ibudo ti wọn n ko awọn atipo to fẹ faya wọ wọ orilẹede naa si ni ẹnu ibode Bosnia-Herzegovina.

Ninu alaye to ṣe lori iṣẹlẹ naa, alaga ajọ to n mojuto awọn ọmọ Naijiria loke okun, NIDCOM, Abikẹ Dabiri Erewa ni awọn akẹkọ naa ko fi irinajo wọn to ajọ ere idaraya ẹyinori tabili lorilẹede Naijiria, NTTF leti ki wọn to lọ.

O ni ninu awọn marun un to rinrin ajo ọhun, meji ninu wọn ti pada sile lọsẹ meji sẹyin, awọn meji ninu wọn tẹẹ pa sọhun lati beere fun iwe igbelu fawọn atipo, nibẹ ni wahala ti bẹrẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ ijiroro ati ifikuluku laarin awọn alaṣẹ orilẹede Naijiria ati Croatia awọn akẹkọ mejeeji ti gba itusilẹ.