ECOWAS: Buhari nàka àbùkù s'orílẹ̀èdè Libya látàrí aàbò tó mẹ́hẹ l'Afrika

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Buhari ni alafi awọn ara ilu lo yẹ ko jẹ awọn aarẹ ilẹ Afirika logun

Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu atẹ lu orilẹ orilẹede Lybia fun eto aabo to mẹhẹ ni awọn agbegbe iha ilẹ Afirika.

Buhari lo sọ ọrọ yii l'Abuja nibi ipade ti awọn aarẹ ati minisita to wa ni iwọ orun Afirika ṣe, lati wa ojutu si idojukọ awọn alakatakiti ẹsin.

Nibi ipade ọhun ni Buhari tun ti sọ pe iṣẹ ibi awọn alakatakiti ẹsin ni isọro gboogi to n koju iwọ orun Africa.

O ni akoko ti to ni Afirika lati fọwọsowọpọ lọna ati wa ojutu si wahala awọn alakatakiti ẹsin naa.

Buhari mẹnu ba bi awọn onija ẹsin ọhun ṣe pa awọn ọmọ ogun mẹtalelọgbọn ni ipakupa lorilẹede Niger laipẹ yii.

Àkọlé fídíò,

Trump impeachment: Trump kò fìdí janlẹ̀ tán, àmọ́ níbo ni yóò jásì?

Lẹyin naa lo ni orilẹede Naijiria ti ṣe tan lati ṣafẹhinti fun awọn orilẹ-ede mii nilẹ Afririka lati gbogun ti awọn alakatakitii ẹsin ọhun.

Buhari ni alafia awọn ara ilu lo yẹ ko jẹ awọn aarẹ ilẹ Afirika logun.